Gani Adams ni bi Akeredolu ṣe le awọn Fulani darandaran kuro ninu igbo ọba l’Ondo lo dara ju

Iba Gani Adams tí sọ pe ojuṣe ati ẹtọ Gomina Rótìmí Akeredolu ni lati le awon janduku Fulani darandaran kuro nipinlẹ Ondo.
Ninu atẹjade ti Olùrànlọwọ Ààrẹ Ọnakakanfo,  Alhaji Kehinde Aderẹmi, fi sita lo ti ni Ìbá Gani Adams sọ pe ojuṣe gomina ọhun ni labẹ ofin lati pèsè ààbò tó yẹ fun awọn eeyan ipinlẹ ẹ, ati pe kaakiri ipinlẹ Ondo lawọn alejo ọran kan ti wa bayii ti wọn n ko idaamu nla ba araalu.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Akeredolu pàṣẹ fún gbogbo àwọn Fulani darandaran ti wọn wa lawọn inu Igbo ti ijọba ti ya sọtọ ki wọn ko àwọn maaluu wọn kúrò níbẹ, bẹẹ lo fún wọn lọjọ meje pẹlu lati fi ṣe e.
Bi ikede yii ti waye ni ijọba Buhari ti bẹ jade, to sì sọ pé amofin agba ni Akeredolu, ẹni tó si yẹ ko mọ òfin dáadáa ni. Buhari sọ pe igbesẹ to fẹẹ gbe ọhun ko ba oun lara mu rara. Siwaju si i, ijọba Buhari ti ni ki Akeredolu fi awọn Fulani silẹ l’Ondo, ko tete wa ọna mi-ìn gba lori bi aabo yóò ṣe wà dipo bo ṣe fẹẹ le wọn danu.
Ọrọ yii lo mu Gani Adams sọ pe Buhari ko wíire, nitori ohun ti Garba Shehu sọ lorukọ rẹ, bíi ẹni to fẹẹ máa dunkooko mọ ijọba Rotimi Akeredolu ni, bẹẹ lo tun fẹẹ fọrọ ọhun yẹpẹrẹ ijọba ẹ paapaa lori ọrọ aabo.
Ọkunrin naa ni bo tilẹ jẹ pé lara dukia ijọba àpapọ̀ ni awọn igbo ti wọn ya sọtọ wa, sibẹ, abẹ àkóso ijọba ipinlẹ lo wa.
O ni,”Ohun to foju hàn ni pé Garba Shehu ati ọfiisi Ààrẹ paapaa ko mọ ìtumọ igbo ti ijọba ya sọtọ yìí. Iru igbo yìí kì í ṣe ibí tí ẹnikẹni le wọ, afi awọn ti wọn ba gbaṣẹ lati ṣe bẹẹ, bẹẹ lo tun jẹ aaye pàtàkì tí awọn ohun amuṣọrọ bíi igi to niye lori ati aaye pàtàkì fún àwọn eranko wa.


“Iwa afojudi gbaa lawọn Fulani darandaran ti wọn n da ẹran kiri inu igbo yẹn n hu. Bi wọn ṣe n gbe inu igbo yẹn, wọn kò ní i bikita lati bẹ awọn igi olowo iyebiye to wa ninu awọn Igbo yii fi dana. Bakan naa ni wọn tun le pa awọn ẹran inu igbo ọhun paapaa.
“Nibi ti wọn ba pe ni igbo ti ijọba ya sọtọ ki í ṣe ibí tó yẹ ki ẹnikẹni máa gbé, koda to fi dori awọn agbẹ ọmọ ipinlẹ Ondo paapaa.
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti sọ pe lara wahala ti awọn janduku Fulani agbebọnrin yìí ṣe naa ni bí wọn ṣe pa ọmọ Alagba Fasoranti, ti wọn tun kọ lu Alagba Falae, ti awọn ọba meji paapaa fara gba ninu iwa janduku wọn l’Ondo. Gani Adams sọ pe “Agbegbe Akoko ni mo ti wa, gbogbo igbo ti ijọba ya sọtọ ni awọn darandaran ti gba pata, ohun ti ijọba Akeredolu ṣe yíi dun mọ wa ninu daadaa.”
Ni bayii, Iba ti ke sí gbogbo ọmọ Yorùbá pata lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn gomina ilẹ Yoruba lati gbógun ti awọn janduku Fulani darandaran ti wọn n da ilẹ Yoruba laamu.
Gomina Akeredolu naa ti sọ pe oun ṣì duro lori ọrọ ti oun sọ yii pe ki awọn Fulani darandaran atawọn maaluu ti wọn fi n jẹ ko kuro ni igbo ọba  l’Ondo.

Leave a Reply