Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nibi ipade eto aabo ilẹ Yoruba, (South West Security Stakeholders’ Group)SSSG, eyi ti Iba Gani Adams, Aarẹ-Ọna-Kakanfo Ilẹ Yoruba, gbe kalẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ yii, l’Abẹokuta, ni ọkunrin naa ti sọ ọ di mimọ pe ko din ni biliọnu mẹta naira ti Yoruba ti san fun awọn ajinigbe to n ji wọn lọmọ gbe lọ.
Aarẹ ṣalaye pe aabo ti sọnu nilẹ yii, to bẹẹ to jẹ ko sẹni to le fẹẹ lọ sawọn apa Oke-Ọya atawọn ibi to tiẹ jẹ apa isalẹ paapaa ti ko ni i maa foya, nitori ijinigbe pọ gidi. O ni awọn to n wọnu oko ba nnkan oko agbẹ jẹ wa nibẹ ti wọn tun n fipa ba wọn laya sun niṣoju wọn.
Bi nnkan ba n lọ bayii, iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni ni o, bẹẹ igi gogoro ma gun mi loju, okeere lo yẹ keeyan ti maa keboosi ẹ ni Aarẹ wi. O ni awọn gomina da Amọtẹkun silẹ, sibẹ, ẹru ṣi n ba gbogbo Yoruba naa ni, nitori ko si aabo. Aarẹ sọ pe ọrọ naa buru debii pe awọn gomina meji lo ti ni kawọn eeyan wọn maa gbe nnkan ija dani lati gbeja ara wọn.
O ni ipade yii ki i ṣe fun oṣelu, bi ko ṣe lati jẹ kawọn agbofinro atawọn ẹgbẹ to wa nikalẹ mọ pe aabo yii ti mẹhẹ na, bi yoo ṣe pada silẹ wa lo yẹ ka maa wa kiri. Lara eto to le da a pada naa si ni dida ọlọpaa ipinlẹ wa silẹ.
Nigba to n sọrọ lori lilo nnkan ija lati daabo bo ara ẹni, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, ẹni ti ACP Bọlanle Muritala ṣoju fun, ṣalaye pe lilo nnkan ija lati daabo bo ara ẹni gba ọgbọn pupọ.
O ni kawọn eeyan, paapaa awọn ẹṣọ alaabo lọna ibilẹ ma ṣe tori eyi ṣi nnkan ija lo, ki wọn ma si ṣe fi ofin sọwọ ara wọn.
Ajogun sọ pe bi ọlọpaa ba ṣi ibọn yin, to pa alaiṣẹ, araalu yoo sọrọ pe o ṣi agbara lo ni. O ni bakan naa lo ri fun araalu tabi agbofinro to fẹẹ gbeja ara ẹ, afi ki wọn ṣọ ọ ṣem ki wọn maa baa tun ko sọwọ ofin.
Ninu ọrọ Ọjọgbọn Olugbenga Akingbẹhin lati Yunifasiti ilu Eko, ọkunrin to wa lẹka ofin ati ẹkọ nipa iwa ọdaran nileewe giga naa sọ ọ di mimọ pe awọn iwa bii ijinigbe, idigunjale, fifẹran j’ẹko oloko, jibiti ori ayelujara, igbanipa, jiju bọmbu, ka ji dukia onidukia atawọn janduku to n gbimọ-pọ daluru ni wọn n pe ni aisi aabo. Ohun naa lo si tumọ si pe aabo ti mẹhẹ.
O ṣalaye pe bijọba ko ba daa, aabo ko ni i si niluu. Bi awọn kan ba n kowo ilu jẹ, aabo ko ni i si niluu, bi aikawe ba n da awọn eeyan ilu kan laamu, ti iṣẹ tun n ṣẹ wọn, aabo ko ni i si nibẹ. Ija ẹsin, ẹlẹyamẹya ati bi oju ọjọ ba ṣe n ri lawọn ibi kan naa si tun maa n ṣokunfa ai si aabo gẹgẹ bi Ọjọgbọn Akigbẹhin ṣe wi.
Lati waa ṣẹgun iṣoro ai si aabo yii, Ọjọgbọn Akigbẹhin ni ki awọn ẹṣọ alaabo pọ si i. Awọn fijilante, OPC, Amọtẹkun ti ijọba yoo maa ran lọwọ. Bẹẹ lo ni ki idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ naa bẹrẹ, kijọba ṣe akosilẹ awọn darandaran ati bi wọn ṣe n ṣaye wọn, ki wọn pin ọrọ-aje dọgba, kaye si wa fawọn ti wọn ba fiya jẹ lati sọ tẹnu wọn pẹlu idajọ ododo.
Ọga awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ogun naa sọrọ, Kọmandanti David Akinrẹmi. O ni ko sẹni ti yoo ba iran Yoruba tan iṣoro aabo yii, afi bi wọn ba funra wọn tan an.
Ọna wo ni wọn yoo gba tan iṣoro naa, o ni ki ẹnu Yoruba ṣe ọkan ṣoṣo lakọọkọ, kawọn ẹṣọ alaabo ma si ṣe sọ pe awọn ko ni i ba ara awọn ṣe. O ni fijilante ko gbọdọ loun ko ni i ba Amọtẹkun ṣe, awọn ọlọdẹ ibilẹ ko gbọdọ kọyin sọlọpaa, ki gbogbo wọn jọ maa ṣe lo le mu nnkan yatọ.
Awọn ẹgbẹ alaabo loriṣiiriṣii ti wọn ran aṣoju wa naa sọrọ, kaluku fohun ṣọkan pe ko sohun ti iran Yoruba nilo ju ki iru ipade bayii maa waye loore koore, ki wọn si gbe agbara igbaani jade nibi to ba ti yẹ ki Yoruba ja, kawọn Fulani yee dunkooko mọ wa nilẹ wa.