Ganiyat purọ f’ọkọ ẹ pe oun loyun, lo ba lọọ ji ọmọ ọjọ mẹfa gbe l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọbinrin ẹni ogoji ọdun kan, Ganiyat Abass, lo ti n ka boroboro ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun bayii lori ẹsun pe wọn ba ọmọ tuntun, ọmọ ọjọ mẹfa, lọwọ ẹ.

Ṣe ni wọn ni Ganiyat dọgbọn tan iya ọmọ naa, Jẹmilat Musa, ẹni to ni ailera diẹ, kuro ninu ile pe ko lọọ ra mọinmọin wa laago mẹjọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, to fi ji ọmọ naa gbe.

Nigba ti Jẹmilat pada denu ile ti ko ri ọmọ rẹ mọ lo fariwo ta, oun ati iya rẹ atawọn alajọgbele wọn lagbegbe Agbele, niluu Iwo, si jọ lọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa agbegbe naa leti.

Ko pẹ ti wọn bẹrẹ iwadii kaakiri lọwọ awọn figilante ati awọn ikọ JTF tẹ Ganiyat lasiko to n gbe ọmọ naa sa lọ. Lẹyin ti awọn ọlọpaa mu un ni wọn tun mu afẹsọna rẹ, Aliu Ọlatunbọsun.

Nigba to n ba Alaroye sọrọ, Ganiyat ṣalaye pe oun ko ni nnkan buburu kankan lọkan lati fi ọmọ naa ṣe, ṣe loun kan n ran iya rẹ lọwọ.

O ni nigba toun wa lọmọ ogun ọdun loun ti kọkọ fẹ ọkunrin kan niluu Eko, ṣugbọn ti ko si ọmọ nibẹ, o ni idi niyẹn ti awọn mọlẹbi oun fi sọ pe ki oun maa pada bọ niluu Iwo, ti oun si bẹrẹ si i fẹ Aliu lati ọdun to kọja.

O ni oun ko ṣẹṣẹ mọ Jemilat, bẹẹ naa si ni awọn mọlẹbi rẹ da oun mọ daadaa, o ni nigba to wa ninu oyun, oun maa n fun un lounjẹ nitori ounjẹ loun n ta niluu Iwo.

Lalẹ ọjọ naa, Ganiyat ṣalaye pe oun ra ẹkọ mẹfa sinu apo, nigba ti oun si de ọdọ Jẹmilat, oun fun un ni mẹta ninu ẹ pẹlu igba Naira pe ko lọọ fi ra mọinmọin ti yoo fi jẹ ẹ.

O sọ pe nigba ti Jẹmilat ko tete de loun gbe ọmọ rẹ pọn, ti oun si daṣọ bo o. O ni lẹyin naa loun mori le ọna agbegbe Agbowo ti afẹsọna oun n gbe, oju-ọna si lawọn kan ti mu oun pe oun ji ọmọ gbe.

Ni ti Aliu, o ni lọdun to kọja ni Ganiyat sọ pe oun ti loyun, ti oun si bẹrẹ si i tọju rẹ pẹlu oyun. O ni lọjọ Tọsidee ti iṣẹlẹ yẹn ṣẹlẹ gan an loun ko awọn mọlẹbi oun lọọ ṣe idana Ganiya nitori ẹsin ko gba oun laaye pe ki ẹni ti oun ko ti i san nnkan-ori rẹ maa dana iṣinu fun oun.

O fi kun ọrọ rẹ pe oun ti kọkọ fẹyawo kan ri, ti iyẹn si bimọ kan fun oun, ṣugbọn nitori pe iyẹn ko ṣe ẹsin (Islam) lawọn ṣe tu ka. O ni lẹyin toun pade Ganiya, to si sọ pe oun ti loyun, to si n ṣe ẹsin daadaa, loun ti fọkan balẹ

Aliu ni ti awọn ba fẹẹ lajọṣepọ, Ganiyat ki i gba ki oun sun le oun nikun, o maa n sọ pe ki oun ma sun le oyun, oun ko si mọ pe ki i ṣe oyun lo wa ninu ẹ.

Amọ ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, ti sọ pe laipẹ ni awọn mejeeji yoo foju bale-ẹjọ.

 

 

Leave a Reply