Gbajabiamila ṣabewo si iyawo fẹndọ ti ọmọọṣẹ rẹ yinbọn pa l’Abuja, wọn lobinrin naa ṣẹṣẹ bimọ ni

Olori ile-igbimọ aṣoju-ṣofin, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila, ti ṣabẹwo si iyawo fẹndọ to n ta beba ti ọkan ninu awọn ọlọpaa to n ṣọ ọ ọ yinbọn fun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọse to kọja, nile wọn to wa ni Kwata Village, Mandalla-Suleja, Niger state, nibi to ti kẹdun pẹlu wọn, to si ṣeleri lati tọju ọmọ tuntun ti wọn ko ti i fun ni orukọ ti iyawo oloogbe naa ṣẹṣẹ bi ati awọn mọlẹbi rẹ.

Lọjọbọ,  Tọsidee, ọsẹ yii, iyẹn lasiko ti olori ile-igbimọ aṣoju-ṣofin ọhun n kọja lagbegbe Sẹkiteria ijọba apapọ, niluu Abuja, ni deede aago mẹta ọsan ni Ifeanyi Okereke pade iku ojiji ọhun, nigba ti ọlọpaa tọ n ṣọ Fẹmi Gbajabiamila binu yinbọn fun un lori.

Wọn ni awọn fẹndọ ko ṣẹṣẹ maa pe bo mọto awọn eeyan nla nla ti wọn ba ti kọja lati taja fun wọn, iru ẹ gan-an lo ṣẹlẹ l’Ọjọbọ yii, ki iku ojiji too pa ọkan ninu wọn.

ALAROYE gbọ pe bi wọn ṣe ri mọto olori ile-igbimọ yii ni wọn ti bo o, ti oun naa si fun wọn lowo gẹgẹ bii iṣe ẹ, ṣugbọn ṣadeede ni ibọn dun, bi ọkan ninu awọn fẹndọ ọhun ṣe ba ara ẹ nilẹẹlẹ niyẹn, ti ẹjẹ si bo o loju ẹsẹ.

National Hospital ni wọn sare gbe e lọ, nibẹ naa ni wọn ti sọ pe o ti ku.

Ọjọ Ẹti, iyẹn ọjọ keji ọjọ ti wọn yinbọn pa a yii lo yẹ ki o sọ ọmọ rẹ to ṣẹṣẹ bi lorukọ.

Leave a Reply