Gbajumọ oṣere, Ọmọtọla Jalade, ti ko Koro o

Faith Adebola

Gbajumọ oṣere ori itage nni, Ọmọtọla Jalade-Ekeinde, ti ko arun Korona to wa nita bayii o. Funra obinrin naa lo sọ bẹẹ sori ẹrọ ayelujara Instagram rẹ lanaa ọjọ Abameta, Satide. Obinrin naa kọ ọ sibẹ bayii pe, ‘Gbogbo yin lẹ o ti maa beere ibi ti mo wa lati ọjọ yii. Ohun to ṣẹlẹ ni pe mo ko Koro ni. Mo ti wa ni igbele lati ọjọ yii, o tẹ mi diẹ, ṣugbọn ara mi ti n ya! Ma a tubọ ṣalaye bo ti jẹ fun yin to ba ya.

Ni bii ọsẹ mẹta sẹyin ni Ọmọtọla kọkọ sọ pe ọkọ oun, iyẹn awako-baalu, Mathew Ekeinde, ṣẹṣẹ ribi ko awọn ọmọ oun meji wale lati Amerika ni, pe Koro yi ka wọn mọbẹ, wọn ko si ri ibi jade lati ọjọ naa. Ko sẹni to ti i mọ boya lati ara awọn yii ni Ọmọtọla ti ko kinni naa, tabi o ko lati ibomi-in ni.

 

Leave a Reply