Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Nibamu pẹlu ileri ti Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, ṣe lati ṣewadii ẹsun obitibiti gbese ti Gomina Ademọla Adeleke fi kan iṣejọba Alaaji Gboyega Oyetọla, igbimọ olutọpinpin kan ti bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ naa.
Adeleke lo sọ laipẹ yii pe gbese owo to le ni irinwo biliọnu Naira nijọba Oyetọla fi silẹ fun ijọba toun, ninu rẹ lo si ti gba biliọnu mejidinlogun ni kete to fidi-rẹmi ninu idibo gomina.
Bi iroyin naa ṣe jade ni awọn aaṣofin ti paṣẹ fun awọn lajọ-lajọ ti ọrọ gbese naa kan lati fara han niwaju ile.
Ni bayii, wọn ti gbe igbimọ ẹlẹni-mẹwaa kalẹ lati tọpinpin ọrọ gbese naa, ki wọn ṣewadii to yẹ lati mọ iye gbese gan-an tipinlẹ Ọṣun jẹ.
Ninu atẹjade ti Akọwe iroyin fun Owoẹyẹ, Kunle Alabi, fi sita, akọsilẹ iye gbese tipinlẹ Ọṣun jẹ, eleyii to wa niwaju awọn aṣofin yatọ si nnkan ti Gomina Adeleke gbe jade.
Owoẹyẹ ṣalaye pe ti wọn ko ba tete fi ọwọ to dara mu ọrọ naa, yoo ni ipa buburu lori ipinlẹ yii, yoo si le awọn oludokoowo jinna nibẹ.
Alaga igbimọ to n ri sọrọ akanti araalu nileegbimọ, Ọnarebu Gbenga Ogunkanmi, ati ti eto iṣuna, Ọnarebu Adebayọ Olodo, ni wọn yoo jẹ alaga igbimọ naa.
Awọn ọmọ igbimọ yooku ni Ọnarebu Kofo Adewunmi, Ọnarebu Tunde Ọlatunji, Ọnarebu Michael Adetoyi, Ọnarebu Babatunde Ibirọgba, Ọnarebu Lateef Adebisi, Ọnarebu Babatunde Kọmọlafẹ, Ọnarebu Adiru Abẹfẹ ati akọwe ile, Ọgbẹni Simeon Amuṣan ti yoo ṣe akọwe fun wọn.