Gbogbo agbara ni mo sa lati jẹ ki igbeyawo yii tọjọ-Olori Ṣilẹkunọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Olori Naomi Silẹkunọla to jẹ Olori laafin Adimula telẹ, ṣugbọn to ti kede pe oun ki i ṣe olori ọba mọ bayii ṣalaye pe gbogbo ọna ni oun san lati ri i pe igbeyawo naa ko ja si ibi to ja si yii, ṣugbọn bo ti wu Ọlọrun ni.

O ni ọpọ igba ni oun maa n rẹrin-in, bo tiẹ jẹ pe ni abẹnu, inu oun ko dun. O ṣalaye yii ninu ọrọ apilẹkọ kan to gbe si ori ẹrọ agbọrọkaye rẹ latiṣalaye idi to fi kuro laafin.

Arẹwa obinrin naa ni, “Mo gbiyanju pupọ lati fori ti i, ki nnkan le wa bo ṣe tọ, mo rẹrin-in laarin ipenija nla, ṣugbọn mo ti ri i pe iṣẹ kan ṣoṣo ni mo ni laafin, ohun naa si ni ọmọ mi, nigba ti Ọlọrun si sọ pe o ti tan, o tan naa niyẹn.’’

Awọn to mọ bọrọ naa ṣe n lọ sọ pe o ti n lọ si bii ọsẹ meji si mẹta ti Olori Naomi ti kuro laafin kabiyesi. O kan jẹ pe o ṣẹṣẹ kede ọrọ naa faraye gbọ ni nigba to han pe ọrọ naa ti di igba to ti fọ ti ko see sọ.

Bawọn kan ṣe n sọ pe awọn aburo ati ẹgbọn kabiyesi ni ki i fi awọn olori yii lọrun silẹ ti wọn ki i fi i pẹ laafin ni awọn mi-in n sọ pe oṣelu to wa ninu aafin naa lagbara ju oṣelu ti eeyan n ṣe ni Naijiria ti wọn fi n ṣejọba lọ. Ẹni ti ko ba si to bo ṣe n pera rẹ ko le kori bọ ọ.

Leave a Reply