Gbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ ni mo maa fọrọ lọ lori yiyan igbakeji mi-Atiku

Jọkẹ Amọri
Ẹni ti ẹgbẹ oṣelu PDP fa kalẹ lati ṣoju wọn lasiko idibo aarẹ ti yoo waye lọdun to n bọ, Alaaji Atiku Abubakar ti ni, oun ko ni i ko iyan ẹnikẹni kere ninu gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ naa lasiko ti oun ba n ṣe ipinnu lati yan ẹni ti yoo ṣe igbakeji oun, nitori ẹgbẹ naa ni awọn eeyan to kun oju oṣuwọn to pọ daadaa to le di ipo igbakeji yii mu.
Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to ti n rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati ji giri, si ṣiṣe agbedide ati ipolongo Atiku kaakiri, eyi to pe ni ‘Let Us Activate the Aticulator Drive’.
O ni, ‘‘Lati ibẹrẹ ọsẹ yii ni mo ti n ṣepade pẹlu awọn alẹnulọrọ nipele nipele ninu ẹgbẹ oṣelu PDP. Koko pataki ti ipade yii wa fun ni lati mu ki okun iṣọkan to wa ninu ẹgbẹ wa yin dain-dain si i, ka si ri i pe gbogbo awọn to yẹ la fọrọ lọ lori awọn ipinnu pataki ti a maa maa ṣe lori eto ipolongo ibo wa ti yoo bẹrẹ laipẹ jọjọ.
‘’Loootọ, gbogbo eeyan lo n reti ẹni ti a maa yan gẹgẹ bii igbakeji aarẹ lati dije pẹlu mi, o si jẹ ipinnu to lagbara ti oludjie to ba nikan an ṣe gbọdọ mu ni pataki.
‘‘Bẹẹ ni ko si ariyanjiyan nibẹ pe ẹgbẹ wa ni ọpọlọpọ awọn ọlọpọlọ pipe to si kun oju oṣuwọn ti wọn le bọ si ipo yii. Ohun to ku lọwọ wa lati ṣe bayii ni ka fi gbogbo agbara ati okun to wa ninu wa ṣe ohun gbogbo, ki a le ni eto ipolongo ti yoo ni itumọ.
‘‘Emi pẹlu awọn aṣaaju wa gbogbo ko ni i kaaarẹ, gbogbo ohun to ba si wa nikapa wa la maa ṣe lati ri i pe a fa ẹni to kun oju oṣuwọn kalẹ gẹgẹ bii igbakeji aarẹ ti yoo ṣoju ẹgbẹ wa.’’
Ṣe ọkan ninu wahala to ba awọn ẹgbẹ oṣelu, pataki ju lọ ẹgbẹ APC ati PDP bayii ni ẹni ti wọn yoo yan ni igbakeji wọn ti yoo jẹ itewọgba si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ, ti yoo si le rọwọ mu lasiko eto idibo aarẹ ọdun to n bọ.
O jọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu to gbajumọ mejeeji yii n ṣọ ara wọn lọwọ lẹsẹ ni lati le mọ ẹni ti wọn maa mu ti ko ni i mu ipalara ba ibo awọn adugbo kan to le ran wọn lọwọ lati gbegba oroke.

Leave a Reply