Gbogbo igba tọkọ ba ba mi laṣepọ ni mo maa n daku, mi o ṣe mọ- Bukọla

Ọlawale Ajao, Ibadan

Obinrin oniṣowo kan, Bukọla Ẹjalonibu, ti yari kanlẹ, o loun ko fẹ ọkọ oun, Kọlawọle Ẹjalonibu, mọ nitori oogun lo fi maa n ba oun laṣepọ, gbogbo igba to ba sí ti fóògùn buruku ọhún ba oun laṣepọ loun máa n dákú lọ gbọnrangandan.

Gẹgẹ bo ṣe ṣọ ni kootu ibilẹ Ọja’ba, to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, lọjọ Ẹtì, Furaidee, to kọja, o ni, “Gbogbo igba to ba ti lo oogun to fi maa n ba mi sun yẹn ni mi o ki n mọ ohun tó bá n ṣẹlẹ mọ. Nigba ti mo ba fi máa laju saye bayii, ọsibitu ni mo máa n laju si.

“Ika eeyan ni, o fẹẹ fi mi ṣoogun owo ni. Bàsèjẹ́ ni paapaa, niṣe lo wa si supamákẹ́ẹ̀tì ti mo ti n taja, to sì ba gbogbo nnkan to wa nibẹ jẹ. Gbogbo bi t’oluwarẹ ṣáà ṣe máa bajẹ pata lo n wa.”

O waa rọ ilé-ẹjọ́ lati fopin sí igbeyawo ọdun mẹtalelogun tọ seso ọmọ mẹrin naa kí ọkọ òun too fi abami ibalopọ ran òun lọ sọrun apapandodo.

Ninu awijare tiẹ, Kọlawọle paapaa ṣapejuwe iyawo ẹ gẹgẹ bíi ẹni ti ko nífẹẹ oun rara, ati pe gbogbo ọna lo n wa lati gbẹmi oun.

Ọkunrin oniṣowo yii ṣalaye pe “Ko sí ohun tó fẹ ti mi o ki i ṣe fún un. Mo fi ọpọlọpọ mílíọ̀nù naira ṣí supamákẹ́ẹ̀tì fún un, síbẹ aláìmoore obìnrin yìí tun n yan ale.

“Gbogbo ere to n sa bayii ni lati pa mi kò le baà jogún owo ati gbogbo dukia mi, Ọlọrun ni ko fẹmi mi le e lọwọ.”

Lẹyin atotonu awọn mejeeji, Oloye Ọdunade Ademọla ti i ṣe ọga awọn adajọ kootu ọhun, pẹlu awọn igbimọ rẹ, Alhaji Suleiman Apanpa ati Alhaji Rafiu Raji, ti fopin si igbeyawo ọdun mẹtalelogun ọhun.

Awọn méjì akọkọ to dagba ju ninu awọn ọmọ naa nile-ẹjọ yọnda fún olujẹjọ. Wọn sì pa ọkunrin naa laṣẹ lati máa fí ẹgbẹrun mẹwaa naira (N10,000) ránṣẹ sí olupẹjọ loṣooṣu gege bíi owo ounjẹ awọn abikẹyin mejeeji ti ile-ẹjọ yọnda fobinrin naa.

Leave a Reply