Gbogbo ohun ti mo le ṣe ni mo ṣe ki igbeyawo mi le tọjọ, ṣugbọn ọkọ mi ko ṣootọ pẹlu mi-Yewande Adekọya

Gbenga Amos

Ibẹrẹ ifẹ dun j’oyin lọ, opin ifẹ lo koro bii jogbo, gẹgẹ bii owe awọn agba. Owe yii lo wọ ọrọ gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa kan, Yewande Abiọdun Adekọya, to fi fi ẹdun ọkan rẹ han sode lasiko yii, pẹlu bi igbeyawo ọdun mẹjọ rẹ ṣe fori ṣanpọn.
Yewande sọ iriri rẹ jade laipẹ yii lori ẹrọ ayelujara, ọrọ naa si ti n ja ranyin, tori iyalẹnu lo jẹ fawọn ololufẹ obinrin arẹwa to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta lagbo awọn onitiata ọhun.
Ọkunrin onitiata kan lọkọ Yewande, Iṣọla Abiọdun lorukọ ẹ, ọmọ meji si ni wọn igbeyawo naa ti mu jade.
Ninu ọrọ ti Yewande sọ, o ni “fun odidi ọdun mẹrinla ni ọkunrin yii fi n fiya jẹ mi, o kan maa sọrọ si mi ṣakaṣaka, o fẹrẹ jẹ ojoojumọ aye yii ni mo n wa ẹkun mu, ti mo maa maa bẹ ẹ pe ko tiẹ jọọ, fifẹ han si mi, ko ba mi lo bii iyawo ẹ, ko si ṣojuṣe ẹ gẹgẹ bii ọkọ rere, ṣugbọn ko yi pada. Emi ni mo n gbe ẹru inawo idile wa lati ọdun wọnyi sẹyin, ṣugbọn mi o ṣaroye nipa ẹ ri, gbogbo ohun ti mo ṣaa fẹ ni ki igbeyawo wa yọri si rere. Ṣugbọn niṣe loun fẹẹ maa jaye ori ẹ kaakiri lai bikita pe mo tiẹ wa nibikan.
“Latigba ta a ti jọ bẹrẹ lo ti jẹ pe oriṣiiriṣii obinrin lo n gbe kiri, ṣugbọn nigba kan, mo ro pe o ti yipada ni, tori o yatọ laarin kan, afi bo ṣe ya mi lẹnu lẹyin ta a ti jọ fẹra tan, to jẹ awọn iwa to le da obinrin lori ru lo n hu. Ẹ wo o, ori mi daru tan, diẹ lo ku, ọpẹlọpẹ Ọlọrun, ọpẹlọlọpẹ awọn dokita ati awọn mọlẹbi mi, niṣe ni iba baye mi jẹ patapata. O dun mi wọnu eegun. Gbogbo ọna ni mo fi jẹ oloootọ si i, mo fọkan tan an, mi o si dalẹ ẹ ri. Oun lo gba ibale mi, oun lọkunrin akọkọ laye mi.”
“Ko tiẹ sọ fun mi to fi ko jade, to si fi mi silẹ. Mo ṣi nifẹẹ ẹ, ṣugbọn o ti file aye su mi.”
Bẹẹ ni Yewande sọ ẹdun ọkan rẹ, o si fi ẹri ti ọrọ naa pẹlu awọn fotọ atẹjiṣẹ to waye laarin ọkọ rẹ atawwọn obinrin to n ko kiri .

Leave a Reply