Gbogbo ohun to ba wa ni ikapa mi ni ma a ṣe lati mu orileede yii pada bọ sipo-Tinubu

Jọkẹ Amọri
Aṣiwaju Bọla Tinubu ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bii oludije sipo aarẹ ẹgbẹ APC ti sọ pe pẹlu bi oun ṣe jawe olubori gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, aṣeyọri nla ṣẹṣẹ bẹrẹ fun orileede Naijiria ni.
O sọrọ yii niluu Abuja, lasiko ti wọn kede rẹ gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ naa, to si n ka ọrọ apilẹkọ rẹ pe oun gba lati di aṣoju.

O ṣeleri pe gbogbo ohun to ba wa ni ikapa oun loun maa ṣe lati mu orileede yii pada bọ sipo, ki oun si fopin si iṣekupani to n ṣẹlẹ lojoojumọ.
Tinubu ni a ni lati fi ifẹ lo, ki a si gbaradi lati lati tun ilẹ wa ṣe. O ni ko si ẹsin kan to le gbe ekeji mi.
Tinubu ṣeleri pe awọn ikọ to mọṣẹ daadaa ni oun yoo gbe kalẹ ti oun yoo si ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe a tun orileede yii ṣe.
Igba mẹfa ati mọkanlelaaadọrin (1, 271) ni ibo ti Tinubu ni, nigba ti minisita feto irinna tẹlẹ, Rotimi Amaechi, ni ibo mẹrinlelọọọdunrun, ti Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ni ibo ọjilenigba o din marun-un(231).

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: