Gbogbo Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn oṣiṣẹ yoo fi maa wọṣo adirẹ nipinlẹ Ọṣun bayii

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti kede pe ṣiṣẹ aṣọ adirẹ lọpọ yanturu ati tita rẹ yoo bẹrẹ nipinlẹ naa bayii.

Bakan naa ni gomina pọn ọn ni dandan fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba lati maa wọ aṣọ adirẹ lẹẹkan laarin ọsẹ, iyẹn Ojọbọ, eyi to pe orukọ rẹ ni “Ọjọ Adirẹ Ọṣun”

Lasiko to n ṣe ifilọlẹ ṣiṣe adirẹ naa nibi  ayẹyẹ ‘Ọsẹ Oge’ to wa lati ṣagbelarugẹ lilo aṣọ adirẹ eleyii ti ileeṣẹ aṣa atibudo isẹmbaye l’Ọṣun pẹlu ajọṣepọ Musty Great Development and Alexandria Jones Cultures, ni USA, ṣe ni Oyetọla ti ni ilu aro ti wọn mọ Oṣogbo ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun mọ gbọdọ di gbajugbaja.

O ni igbesẹ naa wa lati ran awọn eeyan leti ọkan lara awọn nnkan to jẹ ami idanimọ ipinlẹ Ọṣun, paapaa, lati ṣi oju Adirẹ Ẹlẹkọ si gbogbo agbaye.

Oyetọla, ẹni ti akọwe ijọba rẹ, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, ṣoju fun ṣalaye pe igbelarugẹ awọn aṣa ti Eledua fi jinnku ipinlẹ Ọṣun jẹ oun logun, nitori yoo tun mu ki eto ọrọ-aje burẹkẹ si i.

O ni yoo tun jẹ orisun ipese iṣẹ fun ogunlọgọ awọn olugbe ipinlẹ Ọṣun, bẹẹ ni awọn oniṣowo atawọn to fẹran aṣa kaakiri orileede yii ati loke-okun yoo lo anfaani naa lati ṣabẹwo sibi.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “A ti bẹrẹ atunṣe oniruuru awọn ibudo aṣa atawọn nnkan isẹmbaye ti a ni kaakiri Ọṣun, bẹẹ nijọba apapọ atawọn abaniṣiṣẹ ti n dowo pọ pẹlu wa lati sọ awọn ibudo yẹn di apewaawo lagbaaye.

“Lati sọ ipinlẹ Ọṣun di aṣaaju ninu aṣa Yoruba, gbogbo Ọjọbọ, Tọsidee, lọsọọsẹ ti di ọjọ ti awọn oṣiṣẹ ijọba yoo maa wọ aṣọ adirẹ bayii, nitori a gbọdọ fi apẹẹrẹ rere lelẹ.

“Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni aṣẹ yii yoo bẹrẹ si i fẹsẹ mulẹ. Mo rọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ yii lati lo anfaani yii fun idagbasoke iṣẹ ti wọn n ṣe”

Gbogbo awọn lookọ-lookọ nidii igbelarugẹ ọrọ aṣa nilẹ yii bii oludasilẹ iwe iroyin Alaroye, Alagba Alao Adedayọ, Iyaafin Nikẹ Okundaye, Oloye Jimoh Buraimon ati Oloye Muraina Oyelami ni wọn rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati ṣagbelarugẹ igbesẹ ijọba naa.

Leave a Reply