Adewale Adeoye
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe kan ti wọn n pe ni Gwange, niluu Maiduguri, nipinlẹ Borno, ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ ọkunrin kan, Isa Abdullahi, ti wọn fẹsun kan pe o tilẹkun mọ iyawo ile rẹ kan fun bii ọdun meji gbako lai jẹ ko yoju sita, ti ki i si i fun un lounjẹ rara, wọn ni awọn eeyan agbegbe ọhun ni wọn maa n fun un lounjẹ lẹẹkọọkan. Ẹsun to fi kan an ni pe ẹmi okunkun n ba a ja.
ALAROYE gbọ pe awọn olugbe agbegbe Gwange, nibi ti Isa n gbe, ti wọn mọ nipa iwa laabi ti baale ile yii hu siyawo rẹ ni wọn lọọ fọrọ rẹ to awọn alaṣẹ ajọ kan to n ja fẹtọọ awọn obinrin atawọn ọmọde laarin ilu naa leti. Awọn alaṣẹ ajọ ọhun ni wọn tara ṣaṣa lọọ fọwọ ofin mu Isa nile rẹ.
Adari ajọ ọhun, Kọmureedi Lucy D Yunana, ṣalaye fawọn oniroyin lakooko ti wọn lọọ fọwọ ofin mu Isa nile rẹ lọjọ Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, pe ọkan lara awọn aradugbo ibi ti Isa n gbe ni wọn waa ṣofofo fawọn. Wọn ni ibanujẹ lo jẹ fawọn, nigba tawọn ṣilẹkun ile ti okunrin yii tọju iyawo rẹ ọhun pamọ si nitori bo ṣe fiya jẹ obinrin naa.
Wọn ni ko sọwọ itọju kankan lara iyaale ile ohun. Oju-ẹsẹ lawọn si ti gbe e lọ si ileewosan ijọba agbegbe naa fun itọju to peye.
Nigba ti baale ile ohun n ṣalaye idi to fi gbe igbesẹ naa, o sọ pe, ‘ki i ṣe idunnu mi rara, ọmọ meje ọtọọtọ lo bi fun mi, ṣugbọn ti gbogbo wọn ku patapata. Lẹyin naa ni ẹmi airi kan n ba a ja, to si n ṣe wanran–wanran laduugbo. Ko ma ba mi loruko jẹ ni mo ṣe kuku so o mọlẹ bii ẹran, boya yoo gbadun.
Awọn alaṣẹ ajọ naa ti sọ pe awọn ọlọpaa ni yoo ba Isa ṣẹjọ lori iwa ọdaran to hu yii, ati pe, o daju pe wọn maa foju rẹ bale-ẹjọ laipẹ yii