Gbogbo ọna abalaye la maa lo lati ṣawari awọn to pin owo tawọn adigunjale ji gbe l’Okeeho

Olu-Theo Ọmọlohun, Oke-Ogun

Onjo tilu Okeho, Ọba Rafiu Oṣuọlale Mustapher, ti sọ ni gbangba pe gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un, titi kan lilo ilana abalaye ati tibilẹ, lati ṣawari awọn ọdọ ilu naa ti wọn fẹsun kan pe wọn pin obitibiti owo ti wọn ri gba pada lọwọ awọn adigunjale to fọ ileefowopamọ First Bank lọjọsi, mọ ara wọn lọwọ.

Ọba alaye naa ṣeleri naa laafin rẹ lopin ọsẹ to kọja yii nigba to n fi aidunnu rẹ han siwa ti awọn kan lara awọn ọdọ ilu naa hu lori ọrọ owo naa, o ni adiyẹ irana lowo ọhun jẹ, ki i ṣe ajẹgbe fẹnikẹni.

Gẹgẹ bo ṣe wi, Ọba Rafiu loun ti ranṣẹ pe ọga agba ileefowopamọ First Bank, ẹka to wa laduugbo Isalẹ Alubọ, niluu Okeho, nibi tawọn adigunjale naa ti ṣọṣẹ, o ni maneja naa ti fidi ẹ mulẹ foun pe owo to to miliọnu lọna ọgọta naira lo sọnu lasiko iṣẹlẹ buruku ọjọ ọhun.

Ọba Rafiu ni oun o tiẹ gbọ si ti iwa tawọn ọdọ naa hu ọhun, afigba tawọn ọtẹlẹmuyẹ lati olu ileeṣẹ ọlọpaa n’Ibadan ya bo ilu Okeho, ti wọn lawọn n wa awọn ọdọ ti wọn fẹsun kan pe wọn pin owo tawọn ole ji gbe.

O fidi ẹ mulẹ pe inu apo yọlẹ ti wọn fi n di irẹsi si bii mẹta lawọn afurasi ọdaran naa di owo ti wọn ji ni banki naa si, wọn lasiko tọwọ ba ọkan ninu awọn ọdaran yii ni awọn ọdọ naa ri owo ti wọn di pamọ yii ni sakaani wọn, ṣugbọn kawọn agbofinro too de lati fi pampẹ ofin gbe awọn afurasi ọhun lawọn ọdọ yii ti pin owo naa mọ ara wọn lọwọ, ti wọn si kọ lati jẹwọ.

Ọba alaye naa ni afaimọ ko ma jẹ awọn ọdọ ti wọn wale waa ṣọdun Ileya lasiko tiṣẹlẹ naa waye ni wọn pin owo yii, ṣugbọn ẹni yoowu ko lọwọ ninu iwa yii, kabiyesi ni gbogbo wọn ni alalẹ ilu Okeho maa foju ẹ han sode.

Ọba naa waa parọwa fawọn obi lati lọọ tẹ awọn ọmọ wọn ninu lori ọrọ yii.

Ẹ oo ranti pe Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje, ọdun yii, lawọn ẹlẹgiri adigunjale ya bo ẹka First Bank to wa niluu naa, ti wọn pa awọn ọlọpaa to n ṣọ ileefowopamọ ọhun, ti wọn si fọ banki naa, ko too di pe ọwọ pada to mẹrin ninu wọn, tawọn ọdọ ilu si dana sun wọn lẹyẹ o sọka.

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni iwadii ṣi n tẹ siwaju lori iṣẹlẹ buruku ọhun.

Leave a Reply