Gbogbo wa ko le sun ka k’ọri sibi kan naa, a gbọdọ gba Naijiria lọwọ awọn aninilara-Mr Macaroni

Dada Ajikanje

Ko ti i sẹni to mọ ibi ti wahala awọn ọdọ kan ti wọn mu ni Lẹkki pe wọn fẹẹ ṣepolongo ta ko bi wọn ṣe fẹẹ ṣi oju ọna marosẹ naa pelu bi wọn ko ṣe ti i pari ijokoo ti wọn n ṣe lori rẹ. Ọkan ninu awọn adẹrin-in-poṣonu ilẹ wa to tun jẹ oṣere, Ọgbẹni Adebọwale Adedayọ, ti sọ pe gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un, Naijiria gbọdọ bọ ninu irejẹ ati agbara awọn aninilara.

O ṣalaye fun akọroyin ALAROYE ki wọn too gba foonu lọwọ rẹ lati ma jẹ ko le ba ẹnikẹni sọrọ mọ lori foonu pe gbogbo wa ko le sun ka kọri si ibi kan naa, bi gbogbo wa ba si n bẹru pe ka ma baa ku, a ko ni i sọrọ, awọn iran to n bọ lẹyin ko ni i sure fun wa, iya ati irẹjẹ naa yoo si maa pọ si i ni.

Adedayọ sọ pe gbogbo wa la ni ẹtọ gẹgẹ bii ọmọ orileede lati ṣe iwọde wọọrọwọ gẹgẹ bo ṣe wa ninu ofin ilẹ wa. O ni ki i ṣe ohun to bojumu bi awọn ọlọpaa ṣe ko ara wọn waa di oju ọna pa lai jẹ pe awọn eeyan naa n ṣe jagidijagan tabi pe wọn jale, ti a ko si si ni abẹ ijọba ologun.

Oṣere yii ni bii igba ti wọn n yagbẹ sori saare awọn ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko iwọde to waye ninu oṣu kẹwaa, ọdun to kọja.

Leave a Reply