Gende marun-un bọ sọwọ ọlọpaa n’Ifọ, ipaniyan ati ole jija ni wọn mu wọn fun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Nitori ai si ọlọpaa loju popo mọ lasiko yii, ọpọ awọn ọmọ ganfe lo n fi ojumọmọ pitu fawọn eeyan. Bo tilẹ jẹ pe gbogbo wọn kọ lọwọ n ba, awọn to bọ sọwọ ọlọpaa lo le sọ. Iru ẹ ni tawọn gende marun-un ti wọn ko sakolo ọlọpaa lagbegbe Ifọ, nipinlẹ Ogun, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla, wọn ni wọn mọ nipa iku ẹnikan to n jẹ Sunday, wọn da awọn eeyan to n kọja lọna, wọn gbowo, gba foonu, wọn si da rogbodiyan silẹ nitosi ọja Ifọ.

Ọwọ aarọ ọjọ Aiku naa ni awọn gende marun-un ti wọn pe orukọ wọn ni Afeez Ọlapade,(Sabiko, ẹni ọdun mejilelogun), Idowu Adebayọ; ọmọ ọdun mejidinlogun, Oduwaye Ṣeyi (Owo aje, ẹni ọdun mejilelogun) Fatai Olude, ẹni ọdun mejilelogun ati Alabi Ṣẹgun toun naa jẹ ẹni ọdun mejilelogun bẹrẹ si i da awọn eeyan lọna pẹlu awọn nnkan ija ti wọn ko dani.

Bi wọn ti n ko jinni-jinni bo wọn naa ni wọn n gba awọn nnkan ti wọn ni lọwọ gbogbo lọwọ wọn. Ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn pe awọn bọisi yii n’Ifọ, wọn ni awọn ni wọn maa n da wahala silẹ lagbegbe naa.

Eyi lo n lọ lọwọ, gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ naa to ALAROYE leti ṣe ṣalaye, ti awọn kan fi pe DPO teṣan ọlọpaa Ifọ, CSP Adeniyi Adekunle, pe awọn janduku ti gbajọba Ifọ o.

Nigba tawọn ọlọpaa debẹ ni wọn ba ọkunrin kan tọjọ ori ẹ to mẹẹẹdọgbọn ninu agbara ẹjẹ, wọn ti ṣa a ladaa yanna yanna. Wọn pada mọ pe Sunday lọkunrin naa n jẹ, wọn gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn awọn dokita ni ọkunrin naa ti dero ọrun.

Ẹnikan ti wọn pe orukọ tiẹ ni Muhammed toun n wa ọkọ tirela naa fara gba ninu iṣẹlẹ yii, oun naa ṣesẹ, bẹẹ ni wọn gba foonu ọkunrin kan ti wọn pe ni Ọlalekan Alade.

Awọn ọlọpaa gba ya awọn janduku to pitu naa, ọwọ wọn si ba awọn marun-un yii. Foonu marun-un ti wọn ja gba lọwọ awọn eeyan lawọn ọlọpaa sọ pe awọn ba lọwọ wọn.

Bi wọn ṣe mu wọn yii ni CP Edward Ajogun ti kilọ fawọn ọdaran eeyan ti wọn ro pe ọlọpaa ko si niluu mọ pe ki wọn ṣiwọ ninu iṣẹ ibi. O ni ọlọpaa wa kaakiri ti wọn n ṣiṣẹ wọn, ẹni ti wọn ba si ka mọ idi ibajẹ, ọwọ kan naa ni wọn yoo mu un.

Leave a Reply