Gende meji ku sodo lọjọ aisun ọdun tuntun n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun to kọja yii, iyẹn lọjọ aisun ọdun tuntun niṣẹlẹ ibanujẹ kan ṣẹlẹ pẹlu bi awọn gende meji kan, Damilare, ẹni ọdun mejila, ati Kamaldeen, ẹni ọdun mẹrinla, ṣe ko sodo Asa, to wa loju ọna Mubọ, lagbegbe Maraba, niluu Ilọrin. Oku wọn ni ajọ panapana gbe jade ninu odo ọhun.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni  Hassan Adekunle, fi sita niluu Ilọrin, lo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn oniroyin pe lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, niṣẹlẹ buruku ọhun ṣẹ, nibi ti awọn ọmọ mọlẹbi kan naa meji ti ko sodo naa, ti Alaaji Ẹlẹja si ta awọn panapana lolobo, ki wọn too waa yọ oku wọn jade ninu odo Asa ti wọn ko si.

Adari ajọ panapana ti waa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lati maa wa lojufo, ki wọn si maa sọ irinsi awọn ọmọ wọn lojuna ati dena iru iṣẹlẹ agbọ-bomi-loju ọhun.

Leave a Reply