Gende mẹtadinlogoji dero ahamọ EFCC n’Ibadan, wọn lọmọ ‘Yahoo’ ni wọn

Faith Adebọla

Teeyan ba ri bi wọn ṣe to wọn sori ila niwaju ileeṣẹ ajọ to n fimu awọn onijibiti danrin nni, EFCC, tọhun aa kọkọ ro pe boya wọn ṣẹṣẹ fẹẹ wọ ileewe giga ni, ṣugbọn awọn eleyii o wọ ileewe o, ahamọ ni wọn rọ wọn da si, mẹtadinlogoji ni wọn, awọn apamọlẹkun-jaye tọwọ ṣẹṣẹ ba n’Ibadan ti wọn n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni ‘Yahoo Yahoo’.

Alukoro ileeṣẹ Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), Ọgbẹni Wilson Uwajuren, ninu atẹjade kan to fi lede sọ pe opin ọsẹ to kọja yii, l’ogunjọ, oṣu kẹjọ, lọwọ awọn ẹṣọ EFCC ba gbogbo wọn ninu ile kan to wa nigboro ilu Ibadan, ibẹ ni wọn ti n kọṣẹ jibiti lilu ọhun.

O ni olobo lo ta awọn nidii tawọn fi bẹrẹ iṣẹ iwadii, awọn si ṣọ irinsi wọn daadaa kawọn agbofinro le ka wọn mọ ibuba wọn.

Orukọ awọn afurasi ọdaran naa ni Akinbọde Fatai to n pera ẹ ni Jimmy, Samod Oyewọle, Iṣọla Labayọ Akinyẹmi, Ridwan Oluwaṣẹgun Ayinde, AbdulKadir Akọlade Ọladokun, Basit Dare Adebayọ, Kudus Tọla Adebayọ, Joseph Ọladeji,  Popoọla Samuel Ayọmide, Peter Oluwaṣeun Ọladọja, Fẹranmi Ayọdeji Ọlakunbi, Khalid Mohammed, Sodiq Salimọn ati James Ayọmide Ọparẹmi.

Awọn to ku ni Kẹhinde Emmanuel Ayọọla, Adewale Adeparọsi Samson, Adeniran Ayọmide, Abiọdun Ọlamide, Ọlaoye Afọlabi Bọlarinwa, Ajibade Sodiq Ayọdeji, Babalọla Ọpẹyẹmi David, Fatunbi Gboluwaga Oludọtun, Abdusalam Mojeeb Ọlọlade, Taiwo Emmanuel Ọlaoluwa ati Oyewọle Oyewunmi Fred.

Ọgbẹni Wilson sọ pe gbogbo wọn lawọn maa fa le ile-ẹjọ lọwọ laipẹ tawọn ba ti pari iṣẹ iwadii nipa wọn ki wọn le fara gba paṣan ofin.

Leave a Reply