Gende mẹtadinlogun ha sakolo NDLEA l’Ogun, egboogi oloro ni wọn ba lọwọ wọn 

Adewale Adeoye

Gende mẹtadinlogun lara awọn ọdaran to n ṣowo egboogi oloro laarin ilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, lọwọ ajọ to n gbogun ti lilo ati gbigbe egboogi oloro nilẹ yii, National Drug Law Enforcement Agency, NDLEA, ẹka tipinlẹ naa ti tẹ, ti wọn si sọ pe gbogbo wọn lawọn maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ yii, latari okoowo tijọba ti fofin de ti wọn n ṣe. 

ALAROYE gbọ niṣe ni ikọ ajọ naa, pẹlu iranlọwọ awọn ẹṣọ alaabo bii Nigeria Security and Civil Defense Corps, iyẹn awọn sifu difẹnsi, atawọn ṣja lati bareeke ‘35, Artilary Brigade’, to wa lagbegbe Alamala, niluu Abẹokuta, lọ kaakiri aarin ilu naa, ti wọn si fọwọ ofin mu gbogbo awọn ọdaran ti wọn n ṣowo egboogi oloro, atawon to n lo o, nibikibi ti wọn ba ti ri wọn.

Lakooko ti wọn lọọ fwọ ofin mu awọn eeyan ọhun ni wọn tun ri awọn ẹru ofin bii ibọn ilewọ kekere kan gba lọwọ ọkan lara wọn.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abẹokuta lori aṣeyọri yii, Ọga agba ajọ ọhun, ẹka tipinlẹ Ogun, Abilekọ Ibiba Odili, dupẹ gidigidi lọwọ awọn ẹṣọ alaabo gbogbo to ran wọn lọwọ ninu iṣẹ takun-takun naa, o si sọ pe ko ni i su awọn rara lati maa fọwọ ofin mu gbogbo awọn afurasi ọdaran ti wọn n owo egboogi oloro nipinlẹ Ogun.

O ni, ‘nie la lọọ kaakiri ilu Abẹokuta, ta a si ri awọn afurasi ọdaran mẹta mu.

Bakan naa la tun ri awọn to n lo egboogi naa mẹrinla mu, awọn kan sa lọ lakooko ta a fẹ fọwọ ofin mu wọn, bẹẹ la tun ri ibọn agbelẹrọ kan ati ọpọ igbo gba lọwọ awọn ọdaran naa.

Nipari ọrọ rẹ, Odili sọ pe awọn yoo maa tẹsiwaju ninu gbigbogun tawọn olokoowo egboogi to lodi sofin ọhun nigba gbogbo nipinlẹ Ogun.

Leave a Reply