Godwin wọ gau, ọmọ ọrẹ ẹ ti ko ju ọdun mẹwaa lọ fipa ṣe ‘kinni’ fun l’Ajegunlẹ

Faith Adebọla, Eko

 Okun ofin ti gbe aparo ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn kan, Godwin Iroro, agbegbe Ajegunlẹ, nijọba ibilẹ Ajerọmi Ifẹlodun, lo n gbe, ṣugbọn akata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, lo wa bayii, ọmọ ọdun mẹwaa, ọmọ ọrẹ ẹ, lo fipa ba laṣepọ.

Atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CSP Adekunle Ajiṣebutu, fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Satide lo sọ iṣẹlẹ yii di mimọ.

Wọn ṣalaye pe baba ọmọbinrin to ṣi n lọ sileewe pamari ọhun, Ọgbẹni Chukwudi Chime, lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kọkanla, pe ki wọn ba oun bi ọmọ oun (ti wọn forukọ bo laṣiiri naa) leere ohun to ṣẹlẹ si i, tori irin rẹ mu ifura lọwọ, niṣe lo si n sa foun, ko fẹẹ jẹwọ ohun to ṣẹlẹ.

Eyi lo mu kawọn ọlọpaa tẹle e, wọn ri ọmọbinrin naa, wọn si ba a sọrọ, lọmọ ba jẹwọ fun wọn pe ọrẹ timọtimọ baba oun, Godwin, lo fipa ba oun laṣepọ nigba ti baba oun ko si nile.

Wọn ni ọmọ mẹrin ni Godwin ti bi, ṣugbọn awọn ọmọ naa ti wa lọdọ iya wọn niluu Asaba, nipinlẹ Delta, lọhun-un, Godwin nikan lo n da gbe, ile kan naa si loun ati ọrẹ rẹ yii n gbe, ile ọhun wa ni ojule karun-un, Opopona Iyalode, l’Ajegunlẹ.

Iwadii fihan pe baba ọmọ ti Godwin ki mọlẹ yii, iya ọmọ naa ti kuro lọdọ baba rẹ. Wọn lọrẹẹ kori-kosun gidi lawọn baba mejeeji, eyi ni ko jẹ kawọn araale yooku tete fura si kurukẹrẹ ẹ lọdọ ọmọbinrin naa, wọn o mọ pe ọrẹ ti n dalẹ ọrẹ ẹ.

Ṣa, wọn dọdẹ afurasi ọdaran naa titi tọwọ fi ba a lalẹ ọjọ naa, ni wọn ba mu un. Ni teṣan, ọkunrin naa jẹwọ pe loootọ loun ba ọmọ ọrẹ oun yii laṣepọ, o ni ẹẹmeji pere ni, Eṣu lo si tan oun.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti gbọ si iṣẹlẹ yii, o si ti paṣẹ pe kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ ṣewadii ijinlẹ lori ẹ, kawọn le taari afurasi ọdaran naa sile-ẹjọ.

Odumosu ni gbogbo awọn ti oniṣekuṣe to n lọwọ ninu iwa ainitiju bii eyi lawọn maa fẹ eruku ata ofin si ni’mu.

Leave a Reply