Gomina Kwara fẹẹ gbe abadofin ti yoo fopin si owo ifẹyinti awọn gomina tẹlẹ dide

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahaman Abdulrazaq, ti kede pe oun yoo gbe obadofin kan lọ sile-igbimọ aṣofin ti yoo fopin si owo ifẹyinti ti awọn gomina ipinlẹ naa tẹlẹ atawọn igbakeji wọn n gba.

Gomina fi ọrọ yii sita ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaiye fi sita ni ọjọ Eti, Furaidee, ọsẹ yii.

O ni gomina ti tẹti si ọrọ awọn araalu lori eleyii pẹlu bi wọn ṣe lodi si i. O ni gẹgẹ bii aṣoju ilu, awọn aṣofin yoo gbe igbimọ dide ti wọn yoo ṣe eto ti gbogbo araalu yoo fi sọ ero wọn lori rẹ.

Lara awọn gomina tẹlẹ tọrọ kan ni Gomina Muhammed Lawal, Sẹnetọ Bukọla Saaraki ati Abdulfatai Ahmed atawọn igbakeji wọn.

Leave a Reply