Gomina Ṣeyi Makinde seleri atilẹyin fawọn eeyan Ibarapa, o ni gbogbo ohun ti wọn ba fẹ loun yoo ṣe

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣabẹwo si ilu Igangan, lagbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, latari akọlu lemọlemọ to n waye lagbegbe ọhun latọwọ awọn Fulani darandaran si awọn agbẹ atawọn araalu, o si ti fọkan awọn eeyan agbegbe naa balẹ pe gbogbo ohun ti wọn ba fẹ loun yoo ṣe.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ ki-in-ni, oṣu keji yii, ni Makinde balẹ siluu Igangan pẹlu awọn ikọ rẹ, titi kan Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Abilekọ Ngozi Ọnadeko, o si ba awọn eeyan ilu naa sọrọ ni gbọngan nla ilu ọhun.
Gomina kọkọ tọrọ aforiji fun bi ko ṣe ṣee ṣe fun un lati ṣabẹwo ṣaaju akoko yii, bo tilẹ jẹ pe gbogbo wahala to n ṣẹlẹ lori ọrọ awọn Fulani, ti Seriki wọn ti wọn le lọ, ti awọn eeyan nla nla ilu naa ti wọn pa nifọnna ifọnṣu ati bi wọn ṣe n fi maaluu ba ire-oko wọn jẹ pata loun n gbọ, ko seyii ti wọn fi di oun leti nibẹ.
O loun ba wọn kẹdun gidi fun awọn eeyan wọn to ti doloogbe ninu awọn akọlu to waye ọhun, o si ṣeleri pe ijọba oun yoo ṣeto lati pese iranwọ ati atilẹyin fawọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn sọwọ awọn Fulani ọdaran ọhun.
Bakan naa ni Ṣeyi Makinde ni oun yoo ri i pe awọn agbẹ ti maaluu awọn Fulani yii ti ba ire oko wọn jẹ ri iranwọ gba latọdọ ijoba laipẹ, ki wọn le pada sẹnu iṣẹ ounjẹ oojọ wọn.
Makinde ni oun ti gbọ ibeere pataki tawọn mẹtẹẹta to ba a sọrọ lorukọ ilu atawọn ọdọ sọ pe awọn ko fẹ Fulani eyikeyii ni gbogbo ilẹ Ibarapa mọ, o loun yoo lọọ ṣiṣẹ lori eyi boun ba ti pada de Ibadan.
Ni ti awọn ile akọku ti wọn fẹsun kan pe ibẹ lawọn Fulani n fi ṣe ibuba wọn ninu igbo, Gomina Makinde ni awọn yoo mọ bi eyi ko ṣe ni i ri bẹẹ mọ laipẹ. O lawọn ẹṣọ Amọtẹkun yoo bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu bayii, wọn yoo si ro eto aabo agbegbe naa lagbara gidi.
Atẹwọ lawọn eeyan fi pade bi gomina ṣe kede pe oun ti fun awọn ikọ Amọtẹkun agbegbe naa ni awọn ọkọ tuntun ti wọn yoo maa fi ṣiṣẹ, oun yoo si ri i pe wọn ko ṣalaini awọn nnkan eelo to yẹ.
O kadii ọrọ rẹ pe, oun ranti bi awọn eeyan Ibarapa ṣe fi ifẹ han soun nigba toun n polongo ibo, o ni “Mo ranti pe inu họọlu (hall) yii ni mo ti ba yin sọrọ nigba ti mo n kampeeni, mo si ranti bi obitibiti ero ṣe tu jade waa yẹ mi si nigba yẹn, tẹ ẹ si tun dibo fun mi. Ni bayii, ti ẹyin eeyan mi ko ba le sun kẹ ẹ di oju yin mejeeji, awa tẹ ẹ ran niṣẹ naa ko gbọdọ sọ pe a n sun oorun a-sun-han-anrun nibi kan.”
Ṣaaju lawọn to ba gomina naa sọrọ ti fi ẹdun ọkan wọn kan, ti wọn si fun gomina ni ẹkunrẹrẹ akọsilẹ awọn ti Fulani ti ṣe lọṣẹ atawọn dukia wọn to bajẹ. Bakan naa lawọn ọdọ gbe akọle oriṣiiriṣii dani lati fi ẹdun ọkan wọn han, ati lati sọ ohun ti wọn fẹ fun gomina ati ikọ abẹwo rẹ.

Leave a Reply