Gomina Abdulrazaq ṣabẹwo sileeṣẹ tẹlifiṣan NTA Ilọrin to jona

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Lalẹ ana, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Gomina ipinlẹ KwaraAbdulrazaq Abdulrahman, ṣabẹwo sileeṣẹ tẹlifiṣan tijọba apapọ, NTA, to wa lagbegbe Fate, niluu Ilọrin, nibi ti ijamba ina ti ba dukia olowo nla jẹ.

ALAROYE gbọ pe nnnkan bii aagọ mọkanla alẹ ọjọ Iṣẹgun yii nijamba ina naa ṣẹlẹ. Abdulrazaq pẹlu Kọmiṣanna fun iṣẹ-ode, Onimọ-Ẹrọ Rotimi Iliyasu, ni wọn jọ lọ sibẹ lati wo bi iṣẹlẹ naa ṣe ri atawọn ohun to bajẹ nibẹ.

Ina to ṣadeede ṣẹ yọ ọhun jo awọn ọfiisi kan ati apa kan lara ọfiisi igbohun-safẹfẹ. Ko sẹni to mọ pato ohun to ṣe okunfa ina naa.

Ọga agba ileeṣẹ panapana ni Kwara, Waheed Iyanda Yakubu, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mọkanla kọja ogun iṣẹju ni wọn tẹ ileeṣẹ naa laago lati fi to wọn leti.

O ni iwadii ṣi n lọ lati mọ ohun to fa ijamba ina naa.

Leave a Reply