Gomina AbdulRazaq fi aidunnu rẹ han si bawọn eeyan ko ṣe jade dibo ni Kwara

  Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ni nnkan bii aago kan ku iṣẹju mẹẹdogun Gomina ipinlẹ Kwara AbdulRahman AbdulRazaq, ni ibudo idibo rẹ to wa ni Digba PU 004, ni Wọọdu Adewole, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, o rọ awọn araalu ki wọn jade dibo.

Gẹgẹ bi eto idibo funpo gomina ati ileeasofin ṣe n lọ lọwọ jakejado ilẹ yii, awọn oludibo ko fi bẹẹ jade dibo ni Kwara, ṣe ni awọn eeyan ta ku sile. Lasiko ti Gomina AbdulRazaq, dibo lo fi aidunnu rẹ han lori eleyii, to si rọ gbogbo ọmọ Kwara ki wọn jade lọpọ yanturu lati ṣe ojuse wọn.

Sẹnetọ ti wọn sẹsẹ dibo yan ninu ẹgbẹ oselu All Progressive Congress (APC), Sẹnetọ Lọla Ashiru, to ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ọffa, nipinlẹ naa, sọ pe idibo naa n lọ ni irọwọ-rọsẹ ugbọn awọn oludibo ko fi bẹẹ jade dibo, ati pe idibo ti wọn  sun siwaju pẹlu ọsẹ kan lo okunfa bi awọn eeyan ko ṣe jade. O fi kun un pe ọpọlọpọ awọn to rin irin-ajo wale lati waa dibo aarẹ ti wọn ti pada siluu ti wọn gbe.

Leave a Reply