Gomina Adeleke ṣabẹwo sawọn aṣofin Ọṣun, o beere fun atilẹyin wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ṣabẹwo sawọn aṣofin ipinlẹ naa lati beere fun ifọwọsowọpọ ati atilẹyin wọn lati mu ipinlẹ naa tẹsiwaju.

Nibẹ ni Adeleke ti ṣalaye pe niwọn igba to jẹ pe ijọba maa n tẹ siwaju ni, iṣẹjọba oun ko ni i pa awọn akanṣe iṣẹ tijọba ana n ṣe lọwọ ti rara.

O tun ṣẹleri lati ri i pe ibaṣepọ to dan mọran to ti wa laarin awọn igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun atawọn aṣofin tẹ siwaju, pẹlu ileri lati pese gbogbo nnkan ti wọn ba nilo fun ofin to ja gaara loorekoore.

Adeleke ke si gbogbo awọn araalu lati ṣatilẹyin fun iṣejọba rẹ ni bayii ti idibo ti bọ sẹyin, nitori ijọba nikan ko le da a ṣe, oun si ti ṣetan lati gbe iṣejọba to duroore kalẹ.

O ṣeleri ijọba alakooyawọ ti ko ni i yan ẹnikẹni jẹ, ti yoo si mu ki alaafia jọba kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

Ninu ọrọ rẹ, Olori ile naa, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, ṣeleri pe awọn aṣofin yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu gomina, o ni ti awọn ba ni ariyanjiyan lori ohunkohun, o gbọdọ jẹ lori ilana ofin, ki i ṣe ti itara asan.

O ni ibasọrọ loorekoore gbọdọ wa laarin awọn igbimọ alaṣẹ atawọn aṣofin, lati le dena iroyin eke ati ahesọ ti ko lẹsẹ nilẹ. Adeleke ni awọn aṣofin ni ojuṣe fun awọn araalu, eyi si yatọ si ọrọ oṣelu patapata.

Owoẹyẹ ke si gomina lati ri i pe awọn eeyan olorukọ rere, ti wọn ni arojinlẹ, ni wọn yi i ka, lati le ya agbara sọtọ kuro ninu igbero ẹtọ ọmọniyan.

 

Leave a Reply