Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, ti ki ojugba rẹ lati ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Seyi Makinde, ku oriire wiwọle rẹ lẹẹkeji gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa.
Ninu iwe ikini ku oriire to buwọ lu funra rẹ to fi ranṣẹ si Makinde ti wọn jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa lo ti sọ pe bi awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ṣe dibo fun Makinde to fi wọle lẹẹkeji yii fi igbagbọ ti wọn ni ninu iṣejọba rẹ gẹgẹ bii eyi to n ṣiṣẹ takuntakun mulẹ.
Adeleke ni, ‘‘Mo ki arakunrin mi, Ṣeyi Makinde, fun bi wọn ṣe tun dibo yan an lẹẹkeji. Awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ti fi igbagbọ ati igboya ti wọn ni ninu iṣejọba daadaa to n ṣe mulẹ. Wọn ti fidi awọn iṣe idagbasoke daadaa ti Arakunrin mi, Ṣeyi Makinde, n ṣe nipinlẹ Ọyọ mulẹ.
‘‘Ni orukọ awọn eeyan ati ijọba ipinlẹ Ọṣun, ni a ki gomina ku oriire. Bẹẹ la si n foju sọna fun ajọṣepọ ti yoo mu idagbasoke nipa ohun amayedẹrun wa fun ipinlẹ mejeeji lọjọ iwaju. O fi kun un pe bii ibeji to lẹ papọ ni ipinlẹ Ọṣun ati Ọyọ, nipa bayii, ki i ṣe ohun to pọ ju bi ajọṣepọ nipa eto ọrọ-aje, awọn ohun amayedẹrun ati bẹẹ bẹẹ lọ ba pa ipinlẹ naa pọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, ni ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ kede Makinde gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori nibi eto idibo to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, ọṣu Kẹta.
Ijọba ibilẹ mọkanlelogun lo ti rọwọ mu ninu ijọba ibilẹ mẹtalelogun to wa nipinlẹ Ọyọ, nigba ti alatako rẹ lati inu ẹgbẹ APC, Teslim Fọlarin, mu ijọba ibilẹ meji pere, ti oludije ẹgbẹ Accord, Adebayọ Adelabu, ko si wọle nijọba ibilẹ kankan.
Makinde ati Gomina Adeleke ni gomina meji to wa lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba.
Ibrahim Alagunmu, Ilọrin