Gomina APC mẹrindinlogun ti wa lẹyin Tinubu lati di Aarẹ lọdun 2023 – Adeyẹye

Faith Adebọla

Bo ba jẹ ootọ lọrọ ti minisita tẹlẹ fun iṣẹ ode, Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye, sọ, a jẹ pe agba oloṣelu ilu Eko nni, Asiwaju Bọla Tinubu, le bẹrẹ si i fọkanbalẹ lori erongba rẹ lati dupo aarẹ orileede yii lọdun 2023, tori wọn ni awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC mẹrindinlogun lo ti gba lati ṣatilẹyin fun Tinubu.

Adeyẹye to jẹ alaga apapọ fun ẹgbẹ to n polongo ibo fun Tinubu, SWAGA-23 (Southwest Agenda for Tinubu) sọrọ yii niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, lasiko ti wọn n ṣeto awọn igbimọ alakooso ẹgbẹ APC lawọn wọọdu ati ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ ọhun, yatọ si awọn ti ẹgbẹ naa ti yan tẹlẹ labẹ idari Gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde Fayẹmi.

O lawọn gomina wọnyi pinnu lati ṣatilẹyin fun Tinubu, nigba ti wọn wo ọgbọn iṣelu ati oṣelu to ni, laakaye rẹ, bo ṣe n dari nnkan ati eto ilu, ati pe ọkunrin naa lawọn ẹmẹwa ati ọmọlẹyin to pọ gan-an kaakiri orileede yii.

“Aṣiwaju Bọla Tinubu maa di Aarẹ orileede yii laipẹ, ọkan ninu awa ta a wa nibi yii si maa di gomina ipinlẹ Ekiti. Inu mi dun pe awọn alakooso ta a ṣẹṣẹ yan yii maa ṣiṣẹ lati mu ka jawe olubori.

Owo ọwọ kaluku la n na lori eto SWAGA, a o gbowo lọwọ ẹnikẹni, awọn ọmọ ẹgbẹ o si lepa owo. Ẹ jẹ ki n sọ fawọn ọdọ pe gomina mẹrindinlogun lo ti fọwọ si i ki Tinubu di aarẹ, ẹru o si ba wọn mọ nigba ti wọn ti ri i bi Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣe gbaruku ti wa nigba ta a fi SWAGA lọlẹ l’Ekoo laipẹ yii.

Ọkunrin naa tun sọ pe awọn igbimọ ti wọn ṣẹṣẹ yan yii ni ojulowo, awọn gan-an ni igbimọ gidi, o ni Ọgbẹni Paul Ọmọtọṣọ ti wọn yan lọjọ Abamẹta to kọja yii ki i ṣe Alaga APC tootọ, wọn lọọ mu un wa lati ibikan ni.

“Eyi ti wọn ṣe ni Satide yẹn, awada kẹrikẹri lasan ni. Njẹ ẹ ri aṣoju ajọ eleto idibo kankan nibẹ. Nigba ti Fayẹmi fẹẹ jade dupo gomina lẹẹkeji lọdun 2018, gbagbaagba la duro ti i, awa la ṣọna bo ṣe jawe olubori, tori ko si ọmọlẹyin kan fun un nigba yẹn. Ṣugbọn ẹgbẹ rẹ kan ti wọn n pe ni Fayẹmi Tọkantọkan Group ni wọn waa n jẹ mudunmudun iṣakoso rẹ, ko ranti awa ta a jẹ ko dori aleefa mọ.”

Leave a Reply