Gomina Benue ti fawọn fijilante ipinlẹ rẹ laṣẹ lati maa gbebọn kiri

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, ti kede pe oun iyatọ patapata maa wa ninu awọn ikọ fijilante tawọn maa da silẹ lati bẹrẹ iṣẹ aabo ipinlẹ ọhun. O ni awọn ẹṣọ alaabo naa aa gbebọn AK-47 kiri, oun si ti faṣẹ si i lati ṣe bẹẹ.

Nibi ipade apero kan lori eto aabo to waye nile ijọba, nipinlẹ ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee yii, ni gomina naa ti la ọrọ ọhun mọlẹ.

Nibi apero naa ni wọn ti sọ pe awọn akọlu to n waye lẹnu ọjọ mẹta yii latọdọ awọn janduku ti fihan pe iṣoro aisi aabo ti kọja agbara awọn agbofinro ijọba lati koju, awọn o si le laju silẹ kawọn janduku sọ ipinlẹ naa di isọ awọn alapata ti ẹjẹ ki i da nibẹ nigba kan.

Gomina naa ni: “Gbogbo awọn fijilante ta a maa bẹrẹ si i lo maa maa gbebọn rin lati daabo bo ara wọn, ki wọn si le gbeja ara wọn loju akọlu awọn janduku ọta wa.”

O tun ṣalaye pe lẹyẹ-o-sọka loun maa bẹrẹ si i gba awọn oṣiṣẹ si ikọ fijilante ti wọn fẹẹ da silẹ ọhun, o ni lati ọmọ ọdun mejidinlogun si aadọta lawọn maa gba siṣẹ naa.

Awọn to pesẹ sibẹ lo anfaani ipade ọhun lati fi atilẹyin wọn han si Gomina Ortom, wọn gboṣuba fun un bo ṣe n fojoojumọ sapa lati gbeja awọn eeyan ipinlẹ ọhun, ti ko si ki ọrọ oṣelu bọ iṣoro aabo to dẹnu kọlẹ yii.

Wọn ni digbi lawọn wa lẹyin gbogbo igbesẹ to ba gbe lati le mu kawọn araalu sun oorun asunpajude, ki wọn si le maa ba iṣẹ ounjẹ oojọ wọn niṣo.

Gomina ni gbogbo ofin to maa mu ko ṣee ṣe fawọn fijilante naa lati gbe ibọn rin lawọn maa bojuto lai fakoko ṣofo, oun ko si ni i sinmi, ayafi tawọn ba rẹyin awọn afẹmiṣofo ti wọn n han wọn leemọ nipinlẹ ọhun.

Leave a Reply