Gomina Dapọ Abiọdun gbesẹ lori ofin konilegbele opin ọsẹ l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Oni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ni ijọba fopin si konilegbele opin ọsẹ to ti n ṣẹlẹ nipinlẹ Ogun latigba ti Korona ti gbode. Gomina Dapọ Abiọdun ni anfaani ijade ti wa fun gbogbo eeyan bayii lopin ọsẹ ati lọjọ gbogbo.

 Bakan naa lo jẹ pe wọn yoo ṣi awọn mọṣalaaṣi kaakiri ipinlẹ yii lonii lati kirun Jimọ, ti wọn yoo si ṣi awọn ṣọọṣi lọjọ Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ yii, kan naa.

 Ki i ṣe pe Korona ti lọ tan patapata bi gomina ṣe wi, ṣugbọn nitori pe ohun gbogbo ṣee fọgbọn ṣe ninu Korona lo jẹ ki anfaani yii ṣi silẹ. Wọn ni kawọn aafaa maa ṣe waasi to n kede pe Korona wa, kawọn pasitọ naa maa fi kọrin iranti ninu isin wọn.

Eyi to si ṣe pataki ju lọ ni titẹle gbogbo ofin to de Korona lati ibẹrẹ  titi de opin pata, ati titẹle awọn alakalẹ mi-in tijọba fi sita.

 Ibi ti Korona de duro lasiko yii nipinlẹ Ogun gẹgẹ bi atẹjade Gomina Dapọ Abiọdun ṣe wi ni pe eeyan ọrinlelaaadọfa ati mẹjọ (1,288) lo ti ni Korona, eeyan igba ati mẹfa (206) lo n gbatọju lọwọ. Awọn mẹrinlelogun (24) ti ku iku Korona, nigba ti onka awọn ti wọn ti ṣayẹwo ẹ fun le lẹgbẹrun meje (7,122)

Leave a Reply