Gomina Dapọ Abiọdun ti fọwọ si ofin to faaye gba awọn ẹbi ọba lati sin wọn nilana ẹsin wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Aba kan to fẹrẹ da wahala silẹ laarin awọn oniṣẹṣe atawọn ọba alaye nipinlẹ Ogun nigba kan, lori pe ki wọn sin ọba alaye nilana ẹsin Islam abi ti Kristiẹni ti gba aṣẹ ijọba bayii. Gomina Dapọ Abiọdun ti buwọ lu u pe ẹsin ti ọba ba n sin ko too ku ni ki wọn fi sin in, awọn ẹbi ọba si ti lẹnu nibẹ, ki i ṣe aṣẹ awọn oniṣẹṣe ni yoo maa mulẹ mọ.

Yatọ si ti ilana sinsin ọba tofin yii faṣẹ si, bakan naa lo tun n ri si ilana ti wọn yoo maa gba yan ọba alaye nipinlẹ Ogun ati ipo ti wọn yoo to wọn si.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, ni Gomina Abiọdun buwọ lu iwe ofin naa l’Oke-Mosan, niṣeju Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna, Akarigbo Rẹmọ, Ọba Babatunde Ajayi ati Olu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle.

Bakan naa ni ofin yii ṣoju abẹnugan ileegbimọ aṣofin Ogun, Ọlakunle Oluọmọ, ẹni to jẹrii si i pe ọkan ninu awọn aba to mi ilẹ naa titi ni gomina buwọ lu yii, nitori o ni i ṣe pẹlu ipade ita gbangba lọpọ igba pẹlu awọn tọrọ kan, ko too di pe o yọri sibi to yọri si yii.

Ninu ọrọ Gomina Dapọ Abiọdun lẹyin to buwọ lu ofin naa tan, o ni ki i ṣe pe ofin yii koyan awọn oniṣẹṣe to n fọba jẹ kere, nitori iṣẹṣe lagba.

Gomina ni ṣugbọn ẹtọ ọmọniyan ko ṣee tẹ loju mọlẹ, ara anfaani ti ẹnikọọkan ni gẹgẹ bii ọmọ orilẹ-ede yii si ni lati ṣe ẹsin to wu u, ki wọn si sin in nilana rẹ to ba gbesẹ.

Gomina sọ pe ofin naa wa lati yanju awuyewuye to maa n waye lori bo ṣe yẹ ki wọn sin ọba ni. O ni lati isinyii lọ, awọn ẹbi ọba to ba gbesẹ lẹtọọ lati paṣẹ lori bi wọn yoo ṣe sin eeyan wọn, iyẹn ko ni ki wọn tapa sawọn ohun ti aṣa ba wi bi gomina ṣe sọ, ṣugbọn nnkan ti yatọ si ti tẹlẹ to jẹ wọn o lẹnu nibẹ rara.

Ninu ọrọ tiẹ, Kọmiṣanna ati olootu eto idajọ nipinlẹ Ogun, Amofin Oluwaṣina Ogungbade, sọ pe ofin yii ti i ṣe akọkọ iru ẹ nilẹ Yoruba waye kawọn ọba alaye le fi kun ojuṣe wọn nipa idagbasoke ipinlẹ yii ni. O loun nigbagbọ pe awọn ipinlẹ mi-in naa yoo kọṣẹ eyi lara Ogun laipẹ.

Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna, dupẹ lọwọ Ọlọrun pe aba yii di ofin loju oun. Kabiyesi sọ pe ati Musulumi ati Kristẹni lo da si aba to dofin ọhun, bẹẹ lo dupẹ lọwọ Gomina Abiọdun to jẹ ko ṣee ṣe.

Olu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle, sọ pe ọpọlọpọ nnkan lo ṣẹlẹ lori ofin yii, ṣugbọn ofin atunṣe ni, to sọ ohun to yẹ ki kaluku mọ fun un.

Bẹẹ ni Akarigbo Rẹmọ, Ọba Babatude Ajayi, sọ pe ofin yii kọja a n sin ọba lasan, nitori gbogbo ohun to ni i ṣe pẹlu awọn ọba lo ti ṣalaye, o si da oun loju pe wẹrẹ lọrọ gbogbo to jẹ tọlọba yoo maa yanju nisinyii pẹlu ofin tuntun naa.

Tẹ o ba gbagbe, awọn oniṣẹṣe  to n ri si etutu ọba ti figba kan lawọn ko fara mọ aba lati maa sin ọba nilana ẹsin Kristiẹni tabi Islam.

Wọn ni wọn ki i ke Aleluyah n’Ipebi, wọn ko si fi Ṣalam alaikum ṣoro ọba ri, ilana etutu ṣiṣe leeyan fi n di kabiyesi alaṣẹ ekeji oriṣa, ilana naa ni yoo si tọ lọjọ to ba ṣipo pada, to darapọ mọ awọn ẹni iṣaaju to ti lọ.

Awọn oniṣẹṣe ko fara mọ awọn aṣofin Ogun ti wọn n gbe aba ọhun yẹwo nigba naa, wọn ni ọrọ to ba gba sisọ ni fitila, ẹni kan ki i sọ ọ bina ba ku.

Ṣugbọn ni bayii ti Gomina fi fofin yanju ọrọ, boya awọn oniṣẹṣe yoo tun wi nnkan kan la o le sọ.

Leave a Reply