Gomina Ekiti tẹlẹ, Ayọ Fayoṣe, ṣabẹwo si Tinubu ni Bourdillon

Jọkẹ Amọri

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, ti ṣabẹwo ṣe ara balẹ si gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, to tun jẹ aṣiwaju ẹgbẹ APC, Bọla Ahmed Tinubu. Ṣugbọn ọkunrin naa sọ pe abẹwo yii ko ni i ṣe pẹlu boya oun fẹẹ darapọ mọ ẹgbẹ APC, o ni PDP loun tọkan-tara.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Lere Ọlayinka, gbe sori ẹrọ ayelujara ni gomina tẹlẹ naa ti sọ pe, ‘Lonii yii, mo ṣabẹwo si Aṣiwaju Bọla Tinubu ni Bourdillon, lati ki i pe ṣe ara mokun si i.

‘‘Ọrọ ilera ẹni ko ni nnkan kan an ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu ti ẹnikan wa. Ni agbegbe wa nibi, a ki i ṣajọyọ awọn eeyan tiwa nigba ti wọn ba wa laye, afi ka maa fọwọ si iwe ibanikẹdun lẹyin ti wọn ba ku tan. Ṣugbọn loju temi, ki i ṣe ọna to yẹ ka maa gba lati gbe igbesi aye wa ree.

‘‘Ni pataki ju lọ, oṣelu gbọdọ wa fun ka ni ifẹ ara wa. Nitori naa, gẹgẹ bi awọn aṣaaju gbogbo ni Naijiria ti ṣe, emi naa darapọ mọ wọn lati ki Aṣiwaju, ati lati gbadura ilera pipe fun un.

‘‘Ṣugbọn fun ẹyin tẹ ẹ maa n ti ọrọ oṣelu bọ ohunkohun ti eeyan ba ṣe tabi to ba sọ, pẹlu abẹwo ti mo ṣe yii o, alẹnulọrọ ati aṣaaju ẹgbẹ oṣelu PDP ti ko yẹsẹ ni mi.’’ Ohun ti Fayoṣe fi pari ọrọ rẹ niyi.

Leave a Reply