Monisọla Saka
Ṣinkin ni inu awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Edo, labẹ isakoso Gomina Godwin Ọbaseki, n dun bayii pẹlu bi gomina naa dẹrin-in pẹẹkẹ wọn nipa ṣiṣe afikun owo-oṣu wọn, ti oṣiṣẹ to kere ju lọ nipinlẹ naa yoo si bẹrẹ si i gba ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira (70,000), gẹgẹ bi owo-oṣu bayii.
Lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lo kede afikun owo-oṣu yii lasiko ti wọn n ṣi ile ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, Nigeria Labour Congress (NLC), ẹka ti ipinlẹ Edo, eyi ti o forukọ rẹ sọri aṣaaju ninu ẹgbẹ oṣiṣẹ, to tun jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ naa, to si tun jẹ aṣofin to n ṣoju apa Ariwa ipinlẹ Edo lọwọ niluu Abuja, iyẹn, Comrade Adams Aliu Oshiomhole.
O ni lọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni eto naa yoo bẹrẹ.
Atẹjade naa ka bayii pe, “Gomina Ọbaseki ṣafikun owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju nipinlẹ Edo, bẹẹ lo tun ṣi ileeṣẹ awọn oṣiṣẹ tuntun, eyi ti o fi orukọ rẹ sọri Comrade Adams Oshiomhole.
“Lasiko to n ṣi ile ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ to ṣe ringindin, ti ko si si iru ẹ lorilẹ-ede yii, to kọ si oju ọna Temboga, Ikpoba-Hill, Benin City, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa, lo sọrọ yii di mimọ. Lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn yoo bẹrẹ si i ṣamulo owo-oṣu oṣiṣẹ tuntun naa’’.
Tẹ o ba gbagbe, gomina yii naa lo kọkọ fi apẹẹrẹ rere yii lelẹ nipa gbigbe igbesẹ oloju aanu yii loṣu Karun-un, ọdun 2022, nigba to kede ẹgbẹrun lọna ogoji Naira (40,000), gẹgẹ bii owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ, yatọ si ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ti ijọba apapọ n san lati ọdun 2019.
Igbesẹ gomina yii lo ṣee ṣe ko mu itura ba awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa, agaga pẹlu bo ṣe jẹ pe ija lati ṣafikun owo-oṣu oṣiṣẹ ṣi n lọ lọwọ laarin awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ, Nigerian Labour Congress (NLC), ẹka ẹgbẹ naa to jẹ ti awọn oniṣowo, Trade Union Congress (TUC), ati ijọba apapọ, nitori inira to ba araalu latari owo iranwọ ori epo ti ijọba yọ, eyi to mu ki ounjẹ atawọn nnkan mi-in gbowo lori laarin ilu.
Nitori ohun ti Gomina Obaseki ṣe yii, ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ mi-in ati paapaa gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria, ni wọn ni ireti pe Aarẹ yoo kede ẹkunwo owo-oṣu tuntun lasiko to ba fẹẹ ba awọn eeyan sọrọ, lọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii, ti i ṣe ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ nilẹ Naijiria.