Gomina ipinlẹ Zamfara ni ki ọga ọlọpaa maa fun awọn araaalu ni lansẹẹsi ibọn kia

Faith Adebọla

Iṣoro aabo to mẹhẹ jake-jado orileede wa, paapaa lapa Oke-Ọya, ti gbọna mi-in yọ pẹlu bi Gomina ipinlẹ Zamfara, Bello Matawalle, ṣe rọ awọn eeyan ipinlẹ rẹ pe ki kaluku wọn to ba nifẹẹ lati ra ibọn ati awọn nnkan ija oloro ti wọn le maa fi daabo bo ara wọn ṣe bẹẹ, o si tun paṣẹ pe ki Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Zamfara maa fun awọn eeyan ti wọn ba fẹẹ gbawe aṣẹ nini ibọn lọwọ ni lansẹẹsi kiamọsa.
Matawalle ni igbesẹ yii pọn dandan tori ipakupa tawọn afẹmiṣofo atawọn agbebọn n pa awọn agbẹ ati araalu ti mu ki ọpọ sa kuro lẹnu iṣẹ aje wọn, ọpọ ko si le lọ soko mọ, eyi si ti n mu ki ibẹru ati ebi gbode kan lagbegbe ọhun.
Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna feto iroyin, Ibrahim Magaji Dosara, fi lede lorukọ ọga rẹ, o ni ijọba ti ṣetan lati ran awọn eeyan to ba fẹẹ ra iru nnkan ija oloro bẹẹ lọwọ.
Atẹjade naa ka lapa kan pe:
“Latari bi iṣẹlẹ awọn agbebọn afẹmiṣofo ṣe tun peleke si i kaakiri ipinlẹ wa, ti ijọba si n ṣiṣẹ kara lati pese aabo fun ẹmi ati dukia awọn olugbe ipinlẹ yii, paapaa lasiko ojo wẹliwẹli to yẹ kawọn agbẹ wa lẹnu iṣẹ oko wọn, ijọba ti pinnu lati gbe awọn igbesẹ pato ti yoo mu adinku ba iwa ọdaran, ijinigbe, ifẹmiṣofo, ati awọn iwa abeṣe mi-in to n di lemọlemọ lẹnu aipẹ yii.
Ọrọ akọlu yii ko fi ijọba lọkan balẹ, a si ti ṣetan lati fun un ni gbogbo ohun to ba gba lọtẹ yii, ka le koju ẹ ni gbogbo ọna pẹlu awọn igbesẹ ti a mẹnuba nisalẹ yii:
“(a) Ijọba ti paṣẹ ki gbogbo eeyan gbaradi lati ni ibọn ti ara wọn, eyi ti wọn yoo maa fi gbeja ara wọn ti awọn agbebọn ba fẹẹ kọ lu wọn, a si ti paṣẹ pe ki kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ wa bẹrẹ si i fun gbogbo awọn to ba fẹẹ ra ibọn niwee-aṣẹ, wọn ko gbọdọ gbegi dina fun ẹnikẹni lati ni ibọn lọwọ. Ijọba maa ṣeranwọ fawọn araalu, paapaa awọn agbẹ, lati ra nnkan ija oloro ti wọn ba nifẹẹ si. A ti pari eto lati ko fọọmu ẹẹdẹgbẹta fun ẹkun iṣakoso Ẹmia mọkandinlogun kọọkan lati ran wọn lọwọ.
“(b) Ki awọn eeyan too ra ibọn ni ki wọn ti kọkọ gba aṣẹ lọdọ kọmiṣanna ọlọpaa, fun amọran ati akọsilẹ.
“(c) A fẹẹ ṣekilọ fawọn araalu pe gbogbo akọsilẹ ati ọrọ ti wọn ba fi silẹ lawọn ibudo ta a maa ṣi fawọn to ba fẹẹ ra ibọn gbọdọ jẹ otitọ, ko gbọdọ si irọ tabi ayederu kankan ninu akọsilẹ naa, titi kan orukọ, adirẹsi, iṣẹ, fọto, ati awọn mọlẹbi onitọhun.
“(e) Ijọba rọ ileegbimọ aṣofin lati tete ṣiṣẹ lori abadofin ti a fi sọwọ si wọn lori ọrọ yii, ka le sọ ọ dofin laipẹ, ki awọn araalu si le bẹrẹ si i gbeja ara wọn bo ṣe tọ.”
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Zamfara gbe igbimọ oriṣii mẹta kalẹ, eyi ti yoo maa ṣe atunyẹwo ati iwadii nipa awọn araalu to fẹẹ ra ibọn, ki wọn too gba wọn laaye lati ṣe bẹẹ.

Leave a Reply