Gomina Kwara ṣedaro Ọba Adeyẹmi, Ẹlẹkan tilu Ẹkan-meje to waja

Stephen Ajagbe, Ilorin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ti ba araalu Ẹkan-meje, nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ, nipinlẹ Kwara, kẹdun iku Ẹlẹkan, Ọba Michael Aṣhaolu Adeyẹmi.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni kabiyesi waja.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin lọfiisi gomina, Rafiu Ajakaye, gbe sita laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, Gomina Abdulrahman ni iroyin ibanujẹ gbaa niku ọba naa jẹ fun ijọba ataaralu.

Abdulrahman tun ba igbakeji abẹnugan ile-igbimọ aṣofin Kwara, ẹni to jẹ ọmọ bibi ilu naa, Ọnarebu Raphael Adetiba, kẹdun ati igbimọ lọbalọba nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ.

O ni kabiyesi naa ti kopa ribiribi ninu idagbasoke ilu Ẹkan-meje, o mu ki irẹpọ wa laarin araalu, eyi lo si mu itẹsiwaju maa ba ilu naa.

Gomina gbadura ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa safẹfẹ rere, ko si tu ẹbi ati araalu ninu.

Leave a Reply