Gomina Kwara dunnu si Owolẹwa, ọmọ Omu-Aran, to di aṣoju-ṣofin l’Amẹrika

Aderohunmu Kazeem

Lati le fi idunnu awọn eeyan ipinlẹ Kwara han si aṣeyọri nla ti ọkan ninu awọn ọmọ wọn, Oye Owolẹwa ṣe ninu ibo to waye nilẹ Amẹrika, Gomina Abdul-Rasaq naa ti ki i ku oriire.

Oye Owolẹwa yii lo wọle gẹgẹ bii aṣoju-ṣofin, ti yoo maa ṣoju fun agbegbe Washington DC, nilẹ Amẹrika lọhun-un, bẹẹ ni Gomina Abdul-Rasaq ti ṣapejuwe aṣeyọri yii bii oriire nla fun ipinlẹ Kwara to ti wa, ati Naijiria lapapọ.

Ninu ọrọ ti gomina ọhun fọwọ si, eyi ti Akọwe eto iroyin ẹ, Rafiu Ajakaye, pin fawọn oniroyin niluu Ilọrin lo ti sọrọ ọhun.

Gomina yii sọ pe, “Lorukọ gbogbo eeyan ipinlẹ Kwara, mo ki ọmọ wa, Oye Owolẹwa, ọmọ bibi ilu Omu-Aran, ku oriire nla to ṣe.’’

Oye Owolẹwa, yii ni eeyan dudu akọkọ ti yoo wọle sipo aṣoju-sofin. Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii gan-an ni wọn kede pe oun lo wọle, tí yóò sì máa ṣoju fun awọn eeyan Washington DC, nilẹ Amẹrika.
Tẹ o ba gbagbe, ọmọ Naijiria mẹsan-an ni wọn kopa ninu eto idibo to waye nilẹ Amẹria lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu oriṣiiriiṣi nilẹ Amẹrika.
Ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun mẹrinlelọgọjọ ni Owolẹwa fi jawe olubori. Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Joyce Robinson-Paul ni Owolẹwa, ọmọ Naijiria, to tun jẹ ọmọ Yoruba lu lalubami ninu ibo ọhun, ti oun naa si ṣe bẹẹ di aṣoju-aṣofin nilẹ Amẹrika bayii.

Leave a Reply