Stephen Ajagbe, Ilorin
Ni imurasilẹ fun agbekalẹ ikọ Ọlọpaa Ibilẹ (Community Policing), ni Kwara, Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, gbe igbimọ oludamọran kan kalẹ ti yoo moju to eto naa fun wọn.
Ni olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Ilọrin ni gomina ti ṣe ifilọlẹ igbimọ ọhun loju Ọga ọlọpaa Kwara, Kayọde Ẹgbẹtokun, atawọn ẹṣọ alaabo ilu mi-in ti wọn wa nikalẹ.
Abdulrahman leri pe ijọba oun ko ni i faaye gba awọn ọdaran ni ipinlẹ Kwara. O ni ifọwọsowọpọ gbogbo araalu lo le mu eto naa ṣe aṣeyọri. O ni oun ni igbagbọ pe eto ọlọpaa ibilẹ yẹ ko ti wa tipẹ lorilẹ-ede Naijiria. O ni iṣẹ wọn dabii ọtẹlẹmuyẹ ti wọn yoo maa fimu finlẹ ati ni ibaṣepọ ni gbogbo igba pẹlu araalu lọna ati dẹkun iwa ọdaran.
O ni ni pataki julọ, yoo fun awọn agbofinro laaye lati ni ibaṣepọ to dara pẹlu araalu, yoo tun ran wọn lọwọ lati gbogun tawọn ọdaran. O ni igbimọ naa yoo jọ ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo lati le gbogun ti awọn ọdaran to fẹẹ maa yọ ipinlẹ Kwara lẹnu.
Awọn to wa ninu igbimọ naa ni Alaga igbimọ awọn ọba, Ọga ọlọpaa Kwara, awọn olori ileeṣẹ agbofinro, awọn adari igbimọ ileeṣẹ ọlọpaa to n ba araalu laṣepọ, awọn aṣoju ẹkun idibo mẹtẹẹta to wa ni Kwara, aṣoju kọọkan lati ajọ to n dari ẹsin musulumi, Nigerian Supreme Council for Islamic Affairs (NSCIA) ati ajọ ọmọlẹyin kristi, Christian Association of Nigeria (CAN).