Gomina Kwara gbe igbimọ oluwadii dide lori owo ti wọn lo n poora nijọba ibilẹ

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Latari iroyin to n kaakiri igboro pe awọn alaṣẹ ijọba kan n yọ miliọnu lọna ọọdunrun-un naira (N300,000) loṣooṣu laṣuwọn awọn ijọba ibilẹ ipinlẹ Kwara, Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣewadii ọrọ naa.

Igbimọ ọhun ti Adajọ Matthew Ọlabamiji Adewara (to ti fẹyinti) jẹ alaga rẹ ni yoo ṣewadii lori iye tawọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara ti gba lati ọwọ ijọba apapọ ati iye ti wọn pin ninu owo tijọba n pa wọle labẹle, bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun to kọja.

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, gbe sita lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ana, awọn ọmọ igbimọ yooku ni: Abilekọ Sabitiyu Grillo ti yoo ṣe akọwe igbimọ naa, awọn aṣoju ẹka ọtẹlẹmuyẹ (DSS) ati ileeṣẹ ọlọpaa, Abilekọ Titilayọ Adedeji, Alaaji Baba Ibrahim, Amofin Aisha Bello Mohammed ati Alhaja Asmau Apalando.

Lara ojuṣe igbimọ naa tun ni lati tọpinpin bi awọn ijọba ibilẹ ṣe na gbogbo owo to wọle sapo wọn lati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2019.

Bakan naa ni wọn yoo ṣewadii boya ijọba ti ya owo kankan lati sanwo oṣu latigba to ti dori aleefa.

Gomina Abdulrahman ni gbedeke ọsẹ meji ni igbimọ naa ni lati pari iṣẹ naa ki wọn si fi abajade wọn sọwọ sijọba.

Laipẹ yii ni kọmiṣanna meji labẹ ijọba Abdulrahman kọju ija sira lori owo ti wọn nijọba n yọ loṣooṣu lapo awọn ijọba ibilẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ti ni ko sohun to jọ bẹẹ, sibẹ awọn araalu, paapaa ẹgbẹ oṣelu alatako, ko janu lori ọrọ naa, wọn ni iwadii to peye gbọdọ waye lori ẹ.

Leave a Reply