Gomina Kwara pa ipo awọn kọmiṣanna marun-un da

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, pa ipo awọn kọmiṣanna rẹ kan da, to gbe wọn lọ si ileeṣẹ mi-in lati maa ba iṣẹ wọn lọ.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, gbe sita lo ti ni awọn tọrọ kan ni; Kọmiṣana feto ibanisọrọ, Ọlanrewaju Muritala ati akẹgbẹ rẹ to n mojuto eto ọgbin ati idagbasoke igberiko, Harriet Adenikẹ Afọlabi Ọshatimẹhin, paarọ ipo.

Kọmiṣanna to n mojuto ọrọ ayika tẹlẹ, Aliyu Mohammed Saifudeen, ti lọ si ileeṣẹ ijọba to n mojuto oye jijẹ ati idagbasoke ilu. Hajia Aisha Ahman-Pategi to n sakoso awọn ijọba ibilẹ ati idagbasoke igberiko ni wọn gbe sileeṣẹ to n mojuto akanṣe iṣẹ (Special Duties).

Kọmiṣana fun akanṣe iṣẹ, Funkẹ Juliana Oyedun, maa pada sileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ ayika.

Gomina Abdulrahman tun lo anfaani ikede naa lati dupẹ lọwọ ileeṣẹ BUA Group, fun ẹbun awọn ọkọ agbokuu-gbalaisan mẹta ti wọn fun wọn. Eyi waye lẹyin tileeṣẹ yii kan naa ti gbe miliọnu ọgọrun-un kan Naira fun ijọba lati gbogun ti arun Koronafairọọsi.

O tun dupẹ lọwọ gbogbo eeyan, to fi mọ awọn ileeṣẹ nla nla ti wọn ti gbe owo ati ẹbun kalẹ lati koju arun naa.

Leave a Reply