Gomina Makinde fẹẹ fiya jẹ awọn Amọtẹkun to yinbọn paayan ni ipinlẹ Ọyọ 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin wakati diẹ ti iroyin gba ilu kan pe ẹṣọ eleto aabo ilẹ Yoruba ta a mọ si Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ, yinbọn paayan niluu Tapa,

Lẹyin ti wọn ti ṣe bẹẹ yinbọn mọ ọlọpaa niluu Ogbomọṣọ lọjọ mẹta ṣaaju, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ iwadii lori awọn iṣẹlẹ naa, wọn ni

gbogbo ẹni to ba jẹbi ninu awọn agbofinro atawọn ọdọ tó dojú ija kọ wọn lawọn yoo fiya jẹ.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, sọ pe, ko si ojuṣaaju kankan nibẹ, eyikeyii to ba jẹbi ẹsun ipaniyan ninu awọn oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun yoo jiya dandan ni.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin fun Gomina Makinde, Ọgbẹni Taiwo Adisa, fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, o ni lori  ikanni abẹyẹfo (twitter) Gomina yii, to n jẹ @seyiamakinde ni gomina ti sọrọ naa lọsan-an ọjọ Ẹti.

O fi kun un pe afojusun ijọba pẹlu idasilẹ ẹṣọ Amọtẹkun ni lati daabo bo awọn araalu ati dukia wọn ni ibamu pẹlu ilakaka ijọba lati ri i daju pe eto aabo fẹsẹ mulẹ si i ni ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Aabo gbogbo ara ipinlẹ Ọyọ lo jẹ ijọba yii logun. A ko ni i kawọ gbera maa woran nigba ti awọn kan ba n dunkooko mọ ẹmi ati igbaye-gbadun awọn eeyan rere ipinlẹ yìí.

Bakan naa, gbogbo araalu naa gbọdọ mọ pe iṣẹ ijọba lawọn Amọtẹkun n jẹ, nitori naa, a o ni i fi ojuure wo ẹni to ba doju ija kọ wọn, ẹni to ba di wọn lọwọ, tàbí pa wọn lara, lasiko ti wọn ba n ṣe ojuṣe ti ijọba gbe fun wọn ṣe nilana ofin yii.”

O waa rọ gbogbo ara ipinle Ọyọ lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro wọnyi, ki alaafia le jọba jake-jado ipinlẹ naa.

Leave a Reply