Gomina marun-un ba Dapọ Abiọdun lalejo, nitori rogbodiyan awọn Fulani ati agbẹ nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Ọfiisi awọn lọbalọba to wa nile ijọba, l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta, ni awọn gomina marun-un ti i ṣẹ ti Ondo, Kano, Zamfara, Niger ati Kebbi ti ba Gomina Dapọ Abiọdun lalejo lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun 2020. Ohun to gbe wọn wa ko ṣẹyin ipaniyan to n ṣẹlẹ lapa kan ipinlẹ Ogun, nilẹ Yewa, iyẹn laarin awọn agbẹ ti wọn jẹ Yoruba atawọn Fulani ti wọn jẹ darandaran.

Ninu ipade naa ni Gomina Dapọ Abiọdun to gba wọn lalejo ti ṣalaye pe ijọba oun ki i ṣe ti onijagidijagan, nitori ipinlẹ alaafia to ko alejo mọra nipinlẹ Ogun. Ṣugbọn bo ṣe jẹ pe awọn kan jokoo sidii ibajẹ ti wọn n gba ẹmi alaiṣẹ yii, gomina sọ pe oun ko ni i fara mọ ọn rara.

 

E yi lo ni o fa a toun fi gbe ikọ oluwadii kalẹ lati mọ awọn to wa nidii ipaniyan naa. Bakan naa lo ni eto ti pari lori awọn ikọ alaabo ti yoo ran awọn agbegbe yii lọwọ, bẹẹ nijọba ti pese awọn ọkọ, ọkada atawọn nnkan eelo ti wọn yoo nilo lati gbe eto aabo ro.

Ninu ọrọ Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje, o ni oju ti la ju bawọn Fulani ṣe n fi ẹran jẹko lasiko yii lọ. Ibujẹ ẹran ti wọn n pe ni ‘Ranch’ lo ni awọn eeyan n kọ laye igbalode ta a wa yii, oun naa lo si yẹ kawọn Fulani asiko yii maa mu lo, nitori ohun to le dẹkun ikọlu ara ẹni niyẹn.

 

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ondo, Amofin Rotimi Akeredolu, ṣalaye pe ko si ọna to daa ju lati daran jẹ lasiko yii ju kikọ ibudo tawọn onimaaluu yoo ti maa fẹran wọn jẹko lọ. Akeredolu sọ pe yatọ si pe ko ni i si ija mọ laarin agbẹ ati Fulani, ilana naa yoo jẹ kawọn ọmọ Fulani ti wọn ṣẹṣẹ n bi, mọ ọna igbalode, wọn ko ni i maa wọgbo kiri nitori pe wọn fẹẹ da maaluu. Kaka bẹẹ, o ni wọn yoo wa nileewe ti wọn yoo maa kẹkọọ si i nipa ohun ti wọn ko mọ ni.

 

Gomina ipinlẹ Niger, Alaaji Sanni Bello, Zamfara, Alaaji Matawalle ati Kebbi, Alaaji Atiku Bagudu, naa kin awọn to sọrọ ṣaaju lẹyin, kaluku wọn bu ẹnu atẹlu ikọlu alainidii to n waye ni Yewa.

Ninu ọrọ Alaaji Muhammed Kabir Labar, olori awọn Miyetti Allah labala ilẹ Yoruba, o ni Fulani naa padanu dukia ninu ikọlu ọhun, ki i ṣe awọn agbẹ nikan.

Labar sọ pe ogun ile, eeyan mẹtalelogun ati maaluu ẹgbẹrun kan lo ba iṣẹlẹ ẹnu ọjọ mẹta yii lọ ni gaa awọn Fulani tawọn kan fina si. Bẹẹ bi iru eyi ba n ṣẹlẹ, ko le si idagbasoke kan gẹgẹ bo ṣe sọ.

Awọn lọbalọba naa wa nikalẹ, lara wọn ni Olu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle. Kabiyesi rọ awọn Fulani lati le awọn ọdaran aarin wọn jade nilẹ Yewa, ki wọn si ṣetan lati gbe ni alaafia pẹlu awọn to gba wọn lalejo.

Awujalẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna, ko wa, ṣugbọn Dagburewe Idọwa, Ọba Y.A Yinusa, wa nikalẹ lati ṣoju kabiyesi, bẹẹ lawọn ọba mi-in wa nikalẹ, wọn pọ daadaa lati sọ ohun ti wọn fẹ.

Awọn agbẹ wa nibẹ pẹlu, awọn ẹṣọ alaabo pẹlu awọn alẹnulọrọ gbogbo.

Leave a Reply