Gomina Oyetọla gbe igbimọ oluwadii lori ifiyajẹni awọn SARS kalẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Nibamu pẹlu aṣẹ ti Igbakeji Aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo, pa pe ki gbogbo awọn gomina gbe igbimọ oluwadii kalẹ lori oniruuru iwa ibajẹ ti awọn ọlọpaa hu, Gomina Oyetọla ti gbe igbimọ ẹlẹni-mejila kalẹ lati ṣiṣẹ naa.

Nigba to n kede orukọ wọn nile ijọba nirọlẹ oni, Oyetọla ṣalaye pe igbimọ naa yoo gba gbogbo ẹdun ọkan awọn araalu jọ lori iwa awọn ọlọpaa, wọn yoo kiyesi ohun gbogbo to rọ mọ ẹsun naa lati mọ boya ẹsun ọhun lẹsẹ nilẹ tabi bẹẹ kọ.

Bakan naa ni wọn yoo dabaa iru ijiya to ba tọ si ọlọpaa to ba jẹbi ẹsun ti awọn araalu fi kan an fun awọn alakooso ileeṣẹ ọlọpaa, bẹẹ ni wọn yoo sọ iru ẹbun gba-ma-binu fun awọn ti ọlọpaa ba ti huwa aida kan tabi omi-in fun.

Lara ojuṣe wọn tun ni lati tuṣu desalẹ ikoko lori bi awọn kan ṣe kọ lu Gomina Oyetọla lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa yii, lorita Ọlaiya, niluu Oṣogbo, ki wọn si mu imọran wa lori ẹ.

Ọṣu mẹfa lawọn igbimọ naa ni lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi gomina ṣe wi, o si rọ wọn lati ṣiṣẹ naa pẹlu ooto inu ati ẹri-ọkan to daju.

Awọn ọmọ igbimọ naa niwọnyi: Adajọ-fẹyinti Akin Ọladimeji ni alaga, Ọjọgbọn Wasiu Oyedokun, Comrade Ismail Abdul Aziz, Ọjọgbọn Grace Akinọla, Biọdun Layọnu SAN, Abayọmi Ogundele Esq, igbakeji ọga-ọlọpaa to ti fẹyinti, Jide Akano, Ọgbẹni Jumọkẹ Ogunkẹyẹde, Teslim Salaudeen, Comrade Oluwaṣẹgun Idowu, alaga awọn agbẹjọro ẹka tilu Oṣogbo, Abdulrahman Okunade, nigba ti Kẹmi Bello yoo jẹ akọwe igbimọ naa.

Leave a Reply