Gomina Oyetọla ko ẹṣọ Amọtẹkun jade l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, ṣe ikọjade awọn eeyan ọtalelọọọdunrun-un ti wọn jẹ ọmọ ikọ alaabo Amọtẹkun, o si ṣelẹri lati tun gba awọn eeyan to din diẹ ni ẹgbẹrin fun iṣeto-aabo labẹle.

Nibi ayẹyẹ naa to waye lori papa iṣere ileewe Wọle Ṣoyinka Government High School, niluu Ejigbo, ni Oyetọla ti sọ pe ko le si idagbasoke nibi ti ko ba ti si aabo to peye fun ẹmi ati dukia awọn araalu.

Ọjọ mẹtalelogun ni awọn eeyan ti wọn yege fun ikọ naa lo niluu Ejigbo fun idanilẹkọọ, oriṣiiriṣii awọn akọṣẹmọṣẹ nipa eto-aabo ni wọn si fun wọn nidanilẹkọọ lati le mura wọn silẹ fun ipenija ti wọn fẹẹ koju.

Oyetọla ṣalaye pe ijọba oun ko ni i figba kankan fi ọrọ aabo ẹmi ati dukia pẹlu igbaye-gbadun awọn araalu ṣere rara nitori awọn nnkan yii ni ọpakutẹlẹ ijọba oun duro le.

O ni eto-aabo to peye ṣe pataki fun imugbooro ọrọ-aje, idi si niyẹn ti iṣejọba oun ko ṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu un latigba ti oun ti de ori aleefa.

Gomina waa gba awọn ẹṣọ naa niyanju lati ṣiṣẹ idaabobo awọn araalu naa pẹlu ikoraẹni-nijaanu, iwa otitọ, ododo ati ijafafa.

Bakan naa lo rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ikọ naa, ki iṣẹ ọhun le rọrun fun wọn, ki alaafia si le jọba kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

O ni ojuṣe Amọtẹkun ni lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn oṣiṣẹ alaabo, awọn fijilante, awọn ọdẹ ati awọn ikọ alaabo to ku kaakiri, ki ibaṣepọ to dan mọnran si wa laarin wọn, ki wọn si tun ba awọn awọn yooku ni ilẹ Yoruba ṣiṣẹ.

Oyetọla fi kun ọrọ rẹ pe mọto ogun (20) nijọba oun ti ra fun iṣẹ awọn Amọtẹkun pẹlu oniruuru awọn nnkan ti wọn ni i ṣe, bẹẹ ni awọn ti gba awọn fijilante ọtadinlẹgbẹrin o din mẹwaa (750) lati maa sọ nnkan to ba n ṣẹlẹ layiika fun awọn Amọtẹkun.

Ninu ọrọ ikini ku aabọ alaga ikọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Ajagun-fẹyinti Ademọla Aderibigbe, o ni o ṣe pataki lati bẹrẹ Amọtẹkun latari eto aabo to ti mẹhẹ kaakiri ilẹ Yoruba bayii.

Aderibigbe dupẹ lọwọ Gomina Oyetọla fun atilẹyin igba gbogbo to n ṣe fun ikọ Amọtẹkun ati gbogbo awọn ikọ alaabo to ku, o si ṣeleri pe ikọ naa ko ni i gbọjẹgẹ ninu ojuṣe rẹ rara.

 

Leave a Reply