Gomina Sanwoolu ti ni arun korona o!

  Jide Alabi

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, naa ti ni arun korona o. Kọmiṣanna fun eto ilera, Ọjọgbọn Akin Abayọmi,  lo kede ọrọ naa ni ọjọ Abamẹta, Satide.

Ọjọ Ẹti ni gomina ya ara rẹ sọtọ latari ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ rẹ to ti ni arun naa.

Oun naa lọ fun ayẹwo, ayẹwo naa si ti jade bayii, eyi to fidi rẹ mulẹ pe Gomina Sanwoolu ti ni arun korona.

Tẹ o ba gbagbe, eyi ni igba keji ti gomina yoo ni arun naa nitori o ti kọkọ ni in, to si pada gbadun, lasiko ti ina arun naa n ran kaakiri.

Leave a Reply

%d bloggers like this: