Gomina Wike naa fẹẹ dupo aarẹ Naijiria

Jọkẹ Amọri

Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesome Wike, naa ti fi erongba rẹ lati dupo aarẹ Naijiria han. O ni oun nikan loun kun oju oṣuwọn lati le ẹgbẹ APC wọle.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni ọkunrin naa sọrọ yii lasiko to ṣabẹwo si Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom. O ni oun n fi erongba oun han ni ipinlẹ naa fun igba akọkọ.

Wike ni oun nikan loun ni ohun to pe fun lati le ẹgbẹ APC kuro nile ijọba, o si ṣeleri pe oun yoo gba ijọba naa fun ẹgbẹ PDP.

O waa rọ awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ naa pe ki wọn fun oun ni tikẹẹti lati dije, ki wọn ma ta ibo wọn, o ni oun ni idaniloju lati le ijọba buruku naa kuro lori aleefa.

Bakan naa lo sọrọ si awọn agbaagba ẹgbẹ ti wọn jọ da ẹgbẹoṣelu naa silẹ, ṣugbọn ti wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in ki wọn too tun pada wa sinu ẹgbẹ PDP. O ni niṣe ni wọn ta ipin idokoowo wọn lasiko ti wọn kuro ninu ẹgbẹ naa, wọn ko si tun le pada wa ki wọn waa sọ pe awọn maa wa nipo awọn oludasilẹ tabi agba ẹgbẹ.

‘Mo ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ yii, lati ọdun 1998 ni mo si ti wa nibẹ, ko si ibi ti mo sa lọ. Idi si niyi ti ohunkohun to ba ṣẹlẹ si ẹgbẹ yii fi maa n jẹ mi logun. Mi o si kaaarẹ.

‘Awọn ti wọn sa lọ lọdun 2015 ni wọn jẹ ka padanu lasiko ibo, ṣugbọn lonii, wọn n sunkun, ṣugbọn ọpọ ninu wa duro, a si pinnu pe PDP ko ni i ku.

Wike ṣeleri pe ti wọn ba fi le yan an sipo gẹgẹ bii aarẹ Naijiria, eto aabo ni oun yoo kọkọ mojuto.

Leave a Reply