Gomina yari o: Ẹ bẹrẹ si i ra ibọn, tawọn janduku ba yinbọn mọ ọn yin, kẹyin naa yin in  mọ wọn

Faith Adebọla

Ọrọ akọlu tawọn janduku agbebọn n ṣe fawọn eeyan agbegbe Oke-Ọya ti gbọna mi-in yọ pẹlu bi Gomina Bello Masari ti ipinlẹ Katsina ṣe gba awọn araalu nimọran pe ki wọn ma ṣe duro de aabo latọdọ ijọba mọ bayii, o ni ki kaluku wọn bẹrẹ si i ra ibọn, ki wọn maa gbeja ara wọn ni.

Gomina Masari sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nigba to lọọ ṣabẹwo sawọn mọlẹbi ti wọn padanu eeyan mẹwaa sinu ijamba ọkọ to waye nigba ti mọto awọn kọsitọọmu kọ lu awọn eeyan naa lọjọ Aje, Mọnde.

Masari sọ fawọn oniroyin pe “afi ka kun fun adura gidigidi pelu ọwọ mimọ, ka bẹ Ọlọrun Ọba fun aforiji ẹṣẹ, pe ko ba wa da sọrọ to wa nilẹ yii.

“Gbogbo wa la gbọdọ dide si iṣoro awọn janduku agbebọn to n han wa leemọ yii, ọrọ aabo to mẹhẹ yii ti kọja fifọwọ lẹran, a o le jokoo ka maa woran ki awọn kan si maa ra ibọn, ki wọn maa ko ibọn waa ka wa mọle, ki wọn maa pa wa bii ẹran lasan, awa naa gbọdọ bẹrẹ si i ra ibọn lati daabo bo ara wa ni.”

Gomina naa ni bawọn eeyan ṣe n gba kamu tawọn agbebọn ba ti kọ lu wọn wa lara ohun to n ki awọn agbebọn naa laya lati tubọ maa kọ lu wọn si i, ati pe nibi ti iṣoro aabo de yii, o ti kọja ọrọ ti a le maa duro de ijọba nikan lati yanju, kawọn araalu naa ṣe gbogbo ohun ti wọn ba le ṣe lori ẹ ni.

Lori ti awọn eeyan ti ọkọ kọsitọọmu sọ doloogbe, Masari ni gbogbo igbesẹ to la ti ofin lọ lawọn yoo gbe lati ri i pe idajọ ododo waye, o lawọn amofin ati awọn agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ naa.

O ni ohun tawọn kọsitọọmu n ṣe ko daa, ko si tẹ awọn lọrun, awọn ko si le fara mọ ọn, wọn o ba a jẹ ileeṣẹ ijọba ju bẹẹ lọ, idajọ ododo gbọdọ waye, awọn yoo si ṣe ohun to yẹ lati tu awọn tọrọ naa kan ninu, bẹẹ lo ṣadura pe Ọlọrun yoo bu ororo itura si ọgbẹ ọkan wọn.

Leave a Reply