Gumi lawọn ologun n lẹdi apo pọ pẹlu awọn agbebọn, lawọn ṣọja ba ni irọ lo n pa

Faith Adebọla

Latari awọn ọrọ ti wọn lo n tẹnu gbajugbaja olori ẹsin Musulumi l’Oke-Ọya nni, Sheik Abubakar Ahmad Gumi, jade laipẹ yii, ileeṣẹ ologun ilẹ wa ti ṣekilọ fun un pe ko ṣọ ẹnu ẹ, tori niṣe lawọn ọrọ to n sọ tubọ n ki awọn janduku agbebọn laya, awọn o si fara mọ ẹnikẹni to ba naka abuku sileeṣẹ ologun.

Gumi ba awọn oniroyin sọrọ l’Ọjọruu, Wesidee yii, ninu ifọrọwanilẹnuwo tileeṣẹ tẹlifiṣan Arise ṣe fun un, o fẹsun kan ileeṣẹ ologun pe iwakiwa awọn janduku agbebọn to n gogo si i lojoojumọ lọwọ awọn kan nileeṣẹ ologun ninu, wọn mọ nipa bi awọn janduku ṣe n ri ibọn ko wọle, ti wọn si sọ iwa janduku di okoowo nla, tori bi ina ko ba l’awo, ko le jo goke odo.

O ni: “Awọn agbebọn wọnyi n ṣiṣẹ pẹlu ọpọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ologun ati awọn agbofinro ilẹ wa ni. Okoowo ni wọn jọ n ṣe, bi ko ba jẹ bẹẹ, bawo lawọn nnkan ija oloro to lagbaraṣe maa gba ẹnubode ilẹ wa kọja bi ki i ba ṣe pe owo ti bọ sapo awọn kan?

“Niṣe la n fọrọ to wuwo yii pa mi-in-din, ko si daa bẹẹ, eyi n mu idarudapọ wa. Ija ẹlẹyamẹya n lọ ni Naijiria, kaka ki ijọba wa lai fi sibi kan, niṣe nijọba kọyin sawọn janduku agbebọn, ti wọn bẹrẹ si i ran ṣọja si wọn lati pa wọn. Ohun ti mo ri to n ṣẹlẹ nipinlẹ Zamfara ati Niger lo jẹ ki n sọ bẹẹ.

Nigba tawọn eeyan ba n sọ pe awọn agbebọn wọnyi n huwa laabi, bẹẹ ni, mo gba, wọn n huwa ọdaran loootọ, wọn n paayan, wọn n jiiyan gbe, wọn n fipa ba obirin laṣepọ, wọn n ṣe oriṣiiriṣii. Ṣugbọn njẹ ẹ tiẹ ti lọ sọdọ wọn wo lati ri ohun toju awọn naa n ri ati laabi ti wọn n ṣe sawọn naa?

Tori naa, dipo tijọba fi maa mura kankan lodi si wọn, ti wọn maa doju awọn ọmọ ogun kọ wọn, ohun tijọba apapọ le ṣe to le mu ki ilu rọgbọ ni ki wọn ba wọn sọrọ, ki wọn jọ wo nnkan sọtun-un sosi, ki wọn si lo awọn ti wọn ba ri i pe wọn lẹmii alaafia laarin wọn lati ṣẹgun wọn.”

Leave a Reply