Gure ọlọbọrọ ati amala iṣu lọkọ mi fẹran ju, o maa n tẹ wọn lọrun gan-an – Abilekọ Ayelaagbe

Obinrin to ba n lo aye ẹ bi iyawo mi ṣe n ṣe yii, ko sọgbọn ki igbeyawo ẹ ma tọjọ – Ọgbẹni Ayelaagbe

Ninu oṣu yii gan-an ni igbeyawo Alagba Olubunmi Ayelaagbe (Onigba ohun lọna ọfun) ati iyawo wọn toun naa n jẹ Olubunmi Ayalaagbe, pe ọgbọn ọdun. Eyi naa lo jẹ ki akọroyin ALAROYE nipinlẹ Ogun, ADEFUNKẸ ADEBIYI, ba awọn tọkọ-taya naa lalejo, ti wọn si ṣalaye irin-ajo naa nikọọkan.

Iyawo lo kọkọ sọrọ, gẹgẹ bii aṣẹ ọkọ. ’’Emi ni Arabinrin Olubunmi aya Ayalaagbe, ọmọ Micheal ati Esther Ṣowande lati Orile Imọ, l’Abẹokuta.

Mo ṣiṣẹ ni Federal Pay Office, Abẹokuta, mo si fẹyinti lẹnu iṣẹ ijọba lọdun 2016. Pẹlu oore-ọfẹ Ọlọrun, mo pe ẹni ọgọta ọdun (60) lọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹta, ọdun 2020.

Emi atọkọ mi ko pẹ nidii ọlọmọge ati ọlọmọkunrin, ko ju oṣu mẹfa lọ lẹyin ta a bẹrẹ ta a fi ṣegbeyawo. Mo ti dagba, mo ti pe ọgbọn ọdun, awọn naa ti pe ẹni ọgbọn ọdun nigba yẹn, nitori oṣu kan naa lo fi ju mi lọ. Federal Pay Office la ti maa n rira, a dẹ tun maa n pade nigboro, wọn aa maa ni awọn fẹẹ fẹ mi, mi o ni i dahun.

Afi nigba ta a pade nibi igbeyawo kan ti wọn fun wọn ni keeki, bi wọn ṣe mu keeki yẹn fun mi niyẹn pe ki n gba. Mo ni mi o fẹ, iyawo wọn ni ki wọn lọọ fun pẹlu awọn ọmọ wọn, wọn dẹ dahun pe iwọ naa niyawo mi. Mo waa gba keeki naa, kaluku dẹ ba tiẹ lọ. Igba to ya ni mo gba fun wọn.

Ohun to jẹ ki n gba lati fẹ ọkọ mi

Mo ri i pe eeyan to laajo ni wọn. Wọn maa beere bawo nile mi, kin ni mo fẹẹ ṣe ati bẹẹ bẹẹ lọ. Mi o ti i wọle wọn rara ti mo ti ri oye pe wọn maa n ro ti ẹlomi-in mọ tiwọn, iyẹn jẹ ki n fẹran wọn, mo dẹ gba lati fẹ wọn. Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun 1990, la ṣegbeyawo nijọba ibilẹ Abẹokuta South, Ake Abẹokuta. O pe ọgbọn ọdun lọjọ kẹjọ, oṣu yii.

Igbesi aye lọkọ-laya nigba ti mo dele ọkọ mi

Ootọ ni pe isunmọni la a mọṣe ẹni, ki i ṣe pe a n ba ara wa ja nigba ti mo bẹrẹ si i ba wọn gbe gẹgẹ bii iyawo. Nnkan ti mo kan ranti ni pe ta a ba jọ n lọ ni titi, irin wọn maa n ya ju temi lọ, mi o ki i le ba wọn rin dọgba, mo maa maa sare lati ba wọn ni. Wọn aa waa maa ni  ‘ọmọbinrin yii, ki lo n ṣe ẹ, o o le rin ni.’’

Emi ni mo maa n kọkọ bẹ wọn ta a ba ja

Ti mo ba ti mọ pe emi ni mo jẹbi, mo maa ri i pe mo bẹ wọn kilẹ too ṣu. Mo gbọdọ bẹ wọn ṣaa ni, ti mo ba dẹ ri i pe wọn n binu, emi maa sinmi, mi o ni i sọ nnkan kan, ti inu wọn ba walẹ, ma a lọọ bẹ wọn.

Awọn nnkan to maa n faja laarin wa

Ti wọn ba wo o pe o yẹ ki n ṣe nnkan kan ti mi o waa ṣe e, wọn maa binu. Wọn maa n fẹ ki n le da nnkan ṣe lai jẹ pe wọn sọ fun mi. Ti mi o ba ṣe nnkan naa, wọn maa binu.

Iye ọmọ ta a bi

Awọn Yoruba sọ pe a ki i ka ọmọ fọlọmọ. Ọlọrun ṣaa fun wa lawọn ọmọkunrin. A dẹ feto si i.

Ounjẹ ti wọn fẹran ju

Gure ọlọbọrọ ati amala iṣu lọkọ mi fẹran ju, ti mo ba ṣe e fun wọn, o maa n tẹ wọn lọrun gan-an.

Ohun ti wọn ṣe fun mi to jọ mi loju ju

Nigba ti iya baba mi ku, a o ti i ṣegbeyawo, ṣugbọn ọkọ mi gbaruku ti mi pupọ, wọn ko eeyan wa, wọn duro ti mi. Nigba ti baba mi naa ku, bẹẹ naa lo ri.

Ohun ti wọn ṣe fun mi to dun mi ju

Keeyan too le sọ pe olorukọ ṣẹ oun, o maa le diẹ o. (Olorukọ la maa n pe ara wa nitori Bunmi ta a jọ n jẹ) Wọn o ṣẹ mi lẹṣẹ kankan ti mo le maa ranti, wọn maa n mu’nu mi dun ni, ọkọ daadaa ni wọn.

Aṣiri to wa nidii bi igbeyawo wa ko ṣe daru titi donii

Ki i ṣe mimọ ọn ṣe awa mejeeji, bi ko ṣe oore-ọfẹ Ọlọrun. A o le sọ pe a o ki i ni ede aiyede, ṣugbọn kilẹ too ṣu lọjọ ta a ba ja, a gbọdọ pari ẹ. Ko si famili to ba wa pari ija ri fun ọgbọn ọdun yii, mi o kẹru jade ninu ile yii ri nitori ija.

Imọran ti mo maa fun awọn ọmọ asiko yii ni ki wọn maa ni suuru, ki iyawo ni itẹriba fọkọ, keeyan si maa gbadura.

Eyi to waa ṣe pataki ju ni pe nnkan ti baale wa ba fẹ, ka ba a fẹ ẹ. Obinrin ko gbọdọ lọọ ra ilẹ ko maa kọle lai sọ fọkọ, ko waa ni oun fẹẹ fi sọpuraisi ọkọ ni, ko daa.

Ibalopọ naa tun ṣe pataki, eeyan ki i sọ pe o rẹ oun tọkọ ba lo ya o. Nitori to o ba sọ pe oo ṣe, to ba fi le jade, o lọ niyẹn o, ati mu ọkunrin bẹẹ wọle pada maa lagbara.

Emi ni Oloye Ọmọwe Micheal Olubunmi Ayelaagbe (Onigba ohun lọna ọfun).

Nnkan to wu mi ti mo fi fẹ iyawo mi ni pe latilẹ, ẹni to jẹ olorukọ mi ni ẹmi yan fun mi lati fẹ.

Mo ti jade iwe ni Reverend Kuti Memorial Grammar School, mo lọọ ṣiṣẹ ọdun kan ni Federal Pay Office, ni mo ri iyawo mi yii.

Nibi igbeyawo kan ta a tun ti pade ni mo tun ran an leti pe ko fẹ mi. Mi o tiẹ ranti pe mo fun un ni keeki lọjọ yẹn, oun lo pada ran mi leti lẹyin igbeyawo wa pe mo foun ni keeki, pe boya iyẹn gan-an ni mo fi mu oun.

Diẹ lo ku ki n ma fẹ iyawo mi yii

Bo ṣe jẹ pe laarin oṣu mẹfa pere la fi fẹra ka too ṣegbeyawo, diẹ lo ku ki n ma fẹ ẹ. Idi ni pe iru ẹjẹ kan naa la ni, ko si yẹ ka fẹra wa bi a ko ba fẹ wahala.

AS ni mi, mi o gbọdọ fẹ ẹni to ni iru ẹjẹ yii, afi ẹni to ba jẹ AA. A ti n mura igbeyawo, bo ṣe de lọjọ naa to mu iwe yii wa fun mi niyẹn, ni wọn ba kọ ọ sinu ẹ pe AS loun naa. Ọkan mi gbọgbẹ pupọ, ṣugbọn mo pinnu pe mi o ni i fa wahala sira mi lọrun, bi eleyii naa ba maa bọ, ko yaa bọ o, mi o le fẹ ẹni to maa bi SS, ọmọ foni-ku-fọla-dide fun mi.

Mo duro ti ipinnu naa, ṣugbọn nigba tawọn eeyan da si i lọtun-un losi, ti mo ti fẹẹ di alaṣeju, mo gba lati tẹsiwaju ninu igbeyawo naa. Paapaa nigba ti wọn ti fun wa lawọn saamu ta a maa maa ka, ti wọn fun wa lasiko ta a maa ji loru gbadura, la ba fẹra wa lọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun 1990.

Iyawo mi o sọ iye ọmọ ta a bi fun ẹ lẹẹkan to o beere, emi maa sọ ọ.

Ọmọ mẹta la bi, ọkunrin lawọn mẹtẹẹta. Nigba ti a bi akọkọ, a ri aanu gba, ọmọ yẹn jẹ AA. A tun bi ikeji, oun naa tun jẹ AA, a bi ẹlẹẹkẹta, oun jẹ AS. Oun nikan naa lo jẹ AS. Aanu ti ko wọpọ la ri gba. Iyẹn lawa mejeeji fi waa wo o pe Ọlọrun ti ṣaanu wa, ka ma kọja aaye wa nipa bibi ọmọ mi-in si i. Ba a ṣe yaa duro lori mẹta yẹn niyẹn. Gbogbo wọn ni wọn ti kawe tan bayii.

Lara aanu temi atiyawo mi ri gba ninu igbeyawo waa ree o. Ṣugbọn mi o le gba ẹnikẹni niyanju lasiko yii lati fẹ ẹni ti ẹjẹ wọn ba ri bakan naa o. Nitori ki i ṣe gbogbo eeyan ni Ọlọrun n ṣaanu fun bo ṣe ṣe e fun wa.

Kẹ ẹ too fẹra yin rara, ẹ kọkọ lọọ ṣayẹwo, ti wọn ba ti ni ẹjẹ yin ko gba kẹ ẹ fẹra yin, ẹ tete yago funra yin o.

Iyawo mi mọ bo ṣe n mu mi walẹ ta a ba ni gbolohun asọ

A ki i ja, a ki i yan odi. Oun to kan le ṣẹlẹ ni pe ti mo ba ni ko ṣe nnkan ti ko ba ṣe e, ma a pa a ti ni, ma a ṣe nnkan yẹn funra mi. Oun naa mọ bo ṣe n mu mi walẹ, to maa fọwọ pa mi lori ninu yara, ija pari niyẹn. O le jẹ lọwọ alẹ, bo dẹ jẹ lọsan-an naa ni toju ba pofiri,o ya naa ni, o mọ bo ṣe n mu mi daadaa jare.

Nnkan to mu ile wa duro titi dasiko yii

Eeyan daadaa niyawo mi, iwa ẹ daa si mi. Ko sẹni to ba wa pari ija ri. Tọrọ ba tiẹ ba fẹẹ le ju, ma a fọ arofọ si i ni, ma a kewi fun un, mo maa mu un walẹ ni. O jẹ ẹni to mọ itọju agba, ko fi ti pe oṣu kan pere ni mo fi ju oun lọ ṣe.

Ohun ti mo le sọ pe o ṣe to dun mọ mi ninu ju ni pe nigba ti iya mi wa niluu ọba ti wọn lọọ ba ọmọ wọn tọju ọmọ, iya iya mi wa nile, ọdọ wa ni wọn n gbe lati 1991, iyawo mi yii lo n tọju iya iya mi, igba ti iya yẹn tun ṣaarẹ agba ti wọn wa lọsibitu, niṣe lo n tọju wọn bii pe iya tiẹ gan-an ni. Oun naa dẹ ṣi niyaa.

Igba ta a dẹ tun maa kọle ta a wa yii, ko ṣahun si mi. O tiẹ ti maa n ṣe nnkan yẹn ko too sọ fun mi, o ran mi lọwọ daadaa.

Ohun ti mo maa n tori ẹ binu si i nigba ta a ṣẹṣẹ fẹra wa

Ki i rin nilẹ, mo maa n ṣaaju ẹ ni. Ṣe ẹ mọ pe eeyan kukuru loun, o maa maa yi rondo ni, emi dẹ ga. Ma a waa maa binu si i pe ko rin nilẹ, ma a ni ṣe ko fẹẹ ba mi rin ni.

Mo tun maa n sọ pe o n dẹgbẹẹ rin, pe ko maa rin daadaa, ko duro giri bii iyawo mi, o dẹ ṣenji irin ẹ, ko dẹ si wahala mọ latigba yẹn.

Imọran mi fawọn iyawo isinyi

Bo o ṣe waa ba mi nile yii, iyawo mi-in aa maa ro pe nnkan kan wa laarin wa ni, aa ni ki lo n wa kiri gan-an. Obinrin to ba n ṣe bẹẹ, igbeyawo ẹ ko le tọjọ.

Ma ronu ohun ti ko ṣẹlẹ, ma gbọ igbọkugbọọ lọdọ awọn ti wọn aa ni awọn ri ọkọ ẹ nibi kan. Obinrin kan ta a jọ ṣiṣẹ ni OGBC ti waa sun sile wa yii ri, iyawo mi ko ba a ja, nitori o mọ pe ilẹ lo ṣu obinrin naa sita.

Obinrin to ba n lo aye ẹ bi iyawo mi ṣe n ṣe yii, ko sọgbọn ki igbeyawo ẹ ma tọjọ, ile ẹ ko ni i daru, ko ṣaa maa gbadura, ko si maa tẹriba fọkọ.

Leave a Reply