Haa, awọn ọlọpaa ti wọn fẹẹ gba ẹgunjẹ si jẹ ki Adisa fi mọto pa obinrin yii

Njẹ ẹ gbọ pe wọn ti pa Stella Okolie, obinrin olukọni kan ni ile-ẹko giga ti Binni. Mọto lo pa a. Mọto ti Anu Adisa n wa ni. Awọn ọlọpaa lo n le mọto naa lọ, afi bara to ya ba obinrin naa nibi to duro si pẹlu ọkọ rẹ ati ọmọ wọn kan, lo ba pa a lẹsẹkẹsẹ.

Ilu Ibinni lọrọ naa ti ṣẹlẹ, loju ọna to lọ si Eko lati Binni, nibi ti obinrin olukọni yii ni ṣọọbu to ti n ta miniraasi ati omi si. Awọn onibaara rẹ lo waa ja ọja fun un, n lo ba duro siwaju mọto wọn lo n ka owo fun wọn. Oun ko mọ pe Anu Adisa to n wa mọto bọọsi kan ti ni wahala pẹlu awon ọlọpaa, ti ọlọpaa kan si ti ko sinu mọto ẹ, ti awọn to ku n le e bọ. Bẹẹ ọgọrun-un Naira ti wọn maa n gba nibẹ ti ko fun wọn ni wọn ni wọn n tori ẹ le e. Nibi ti eyi to wa ninu mọto pẹlu ẹ ti n du siarin mọ ọn lọwọ ni nnkan ti daru, nitori ọwọ mọto yi biripe lọwọ Adisa, apa rẹ ko si ka a mọ, iyẹn ni mọto naa fi ba ere buruku kọ lu Stella ati ọmọọṣẹ rẹ.

Bi Stella ti n kawo fun awọn ọlọja rẹ, bẹe ni ọmọọṣẹ rẹ n gbe ọja ti wọn ko wa wọ ṣọọbu wọn. Ohun t iwọn n ṣe ree t i mọto Adiosa t iawọn ọlọpaa n le fi ya ba wọn, to si pa Stella. Ọsibitu  iwon sare gbe Ọ̄ọọṣe re yi na alọ, ooun ṣi w anib ito it n gatọju. Ọmọ obinri naa kan, Tega,ni ẹbi awọn ko ni i gba eleyii o, pe awọn ọlọpaa to pa iya oun gbọdọ jiya labẹ ofin.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Tori pe wọn yinbọn paayan meji, afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje dero ahamọ l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta Lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un yii, lawọn gende mẹrin …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: