Awọn ọlọpaa Ṣagamu ti mu un o. Abimbọla. Koda wọn tun mu ọkọ ẹ naa, Taiwo Ọnabanjọ, mọ ọn. Wọn si ti ti wọn mọle. Ọmọbinrin kekere yii ni wọn n fiya jẹ, ọmọ ọdun mẹfa pere ni. Ọmọ Taiwo ni o, ọmọ orogun Abimbọla, ṣugbọn ko si iya rẹ lọdọ wọn. Wọn ni niṣe ni Abimbọla yoo mu iṣo, ti yoo maa gba a mọ ọmọ naa lori, ti yoo si maa fi iṣo yii ya a ni gbogbo ara.
Iwe Iroyin Punch ridii ọrọ naa pe awọn araadugbo ni wọn pe ileleṣẹ kan to n ja fun ẹtọ awọn ọmọde, Ọlanrewaju Ọmọ-George Foundation, ti wọn ni ki wọn waa ba awon gba ọmọbinrin kekere kan ti wọn n fiya jẹ ni adugbo Ijagba ni Ṣagamu. Wẹmimọ Adebiyi ti i ṣe agbaninimọran nileeṣẹ naa ṣalaye pe iṣo ni Abimbọla maa n gba mọ ọmọ orogun rẹ lori, ti yoo ni oun n fiya jẹ ẹ nitori o ṣẹ oun, ijiya naa lo si pọ ju loju awọn ara adugbo ti wọn fi ranṣẹ si awọn.
O ni nigba ti awon debẹ paapaa, awọn ara adugbo jade lati jẹrii pe loootọ ni Abimbọla n fiya jẹ ọmọde yii, oju rẹ naa ni wọn si ṣe n sọ ọ. Ohun to jẹ ki awọn ọlọpaa mu un lọ ree, ti wọn si mu Taiwo ọkọ rẹ naa, o sa wa nibẹ to n ri gbogbo eleyii ti ko si ṣe nnkan kan. Wọn ti mu ọmọ yii lọ si ọsibitu fun itọju, wọn si n wa iya to bi i gan-an.