Haa, odo gbe tiṣa lọ l’Ọmi-Adio, wọn ni biriji lo wo lojiji

Aderounmu Kazeem

Ibanujẹ nla lo ṣẹlẹ niluu Ọmi-Adio nijọba ibilẹ Ido niluu Ibadan nipinlẹ Ọyọ nigba ti odo gbe tiṣa kan to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ lọ.

Ọjọ Aje, Mọnde, yii ni wọn sọ pe iṣẹlẹ ọhun waye nigba ti biriiji to wa niluu Igisogba ja lulẹ lasiko ti ojo nla kan rọ.

Nureni Adejumọ ni wọn pe orukọ olukọ to ti fẹyinti ọhun. Oko ni wọn sọ pe o ti n bọ lọjọ naa. Ile ana ẹ gan-an lo fẹẹ ya to fi gbe ọkada ẹ sẹgbẹẹ kan, to si gun biriji onipako to fẹẹ fi sọda sibi to n lọ. Aarin biriji ọhun ni wọn lo rin de, ti biriji onipako yii fi ja mọ ọn lẹsẹ, bi Adejumọ ṣe re sinu odo niyẹn, ti omi si gbe e lọ

Wọn ni gbogbo igbiyanju awọn omuwẹ lati yọ ọ ni ko so eso rere, ti wọn ko si ti i ri titi di asiko yii.

Alaga awọn ọmọ ẹgbẹ OPC agbegbe naa, Muri Adekọla, sọ pe loootọ niṣẹlẹ ọhun waye ni deede aago mẹjọ aṣalẹ ọjọ Aje, bẹẹ lo rọ ijọba ko ṣeto bi biriiji gidi yoo ṣe wa lagbegbe naa, ki irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ le ma waye mọ.

 

 

Leave a Reply